Òṣèré tíátà, ẹ má jẹ́ kí àbùkù wọ ìlàkàkà yín láti kó ọrọ̀ jọ - Ajirebi
Ẹ̀kún omi tó bo ilé mi fún mi ní ìfúnpá gíga, ọ̀pẹ́ Funke Akindele àti Kunle Afod pẹ̀lú ọ̀pọ̀ olólùfẹ́ míì

Iriri nla ni oju agba ọjẹ tiata kan, Alagba Kayode Olasehinde, ti ọpọ eeyan mọ si Pa Ajirebi lagbo tiata ti ri nile aye.
Ta ba si n sọrọ awọn elere tiata to lami laaka, odu ni Ajirebi, kii se aimọ fun oloko nitori awọn isẹ ribiribi to ti gbe se lagbo tiata.
Adẹrinposonu ati alawada to jẹ ilumọọka ni Ajirebi fun ọpọlọpọ ọdun, ti ọpọ eeyan si maa n fẹ lati wo oju rẹ ninu ere tiata.
Amọ bo se n dẹrin pa ọpọ eeyan yii, naa lo ni awọn isoro to n ba finra, eyi ti ko han si ọpọ eeyan, paapaa awọn ololufẹ rẹ.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Alagba Ajirebi sọ ọpọ ohun ipenija to n koju, bi agbo tiata ti ri lasiko yii ati awọn atunse to yẹ ko waye ni ẹka naa.
Ifunpa mi ti ga tori ẹkun omi to bo ile mi, ọpẹ Funke Akindele ati Kunle Afod ti Ọlọrun lo fun mi:
Ọkan lara ipenija nla to ko idagiri ba ọkan agba osere ati alawada naa ni ile rẹ ti ẹkun omi bo ni agbegbe Ikorodu osu keje ọdun 2020.
Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, Ajirebi ni ifunpa oun ti ga kọja aala, tawọn ọmọ ati ẹbi si n rọ oun lati mase jẹ ki isẹlẹ naa gba ẹmi oun.
O ni Kunle Afod lo fi isẹlẹ naa to osere tiata mii lobinrin, Funle Akindele leti, ti onitọun si sanwo filaati kan pe ki oun maa ko lọ sibẹ.
O tun fikun pe Kunle Afod gan tun ke sawọn ololufẹ rẹ lati dide iranwọ fun oun, ti gbogbo wọn si ran oun lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Samuel Ajirebi/Instagram
Ko si ohun to buru ti osere ba se afihan dukia rẹ lori ayelujara amọ o dara ki awọn eeyan ri funra wọn lai pariwo:
Nigba to n sọ ero rẹ lori bi awọn osere tiata kan, paapaa awọn obinrin, se maa n patẹ awọn dukia ti wọn ni sori ayelujara, Ajirebi ni ko si ohun to buru nibẹ.
Amọ o wa yan pe yoo kuku dara ko jẹ pe awọn araalu funra wọn lo ri awọn dukia naa, lai jẹ pe ẹni to ni wọn lo ti kọkọ kede wọn sori ayelujara.
Agba osere naa fikun pe iya ti jẹ awọn osere tiata sẹyin, ti wọn si maa n fi ẹsẹ rin kiri igboro lọdun diẹ sẹyin, amọ ti Ọlọrun ba wa da wọn lohun bayii, o yẹ ki aye mọ.
Bakan naa lo rọ awọn osere tiata to jẹ akẹẹgbẹ rẹ pe ki wọn titori kiko dukia jọ, maa lọwọ ninu awọn isẹ ti ko mọ, amọ ki wn maa jẹ ki ọwọ wọn mọ ni gbogbo igba.
“Elere tiata kii ṣẹ́ṣo, ilaagun wa la n jẹ. O si yẹ ki awọn osere tiata mase jẹ ki abuku wọ ilakaka wọn lati ko dukia jọ.”
Asa kikun ẹfun sori ọmọde bii arugbo tabuku isẹ tiata:
Nigba to n woye lori awọn asa kan to gba agbo tiata kan, paapaa bi awn akẹẹgbẹ rẹ se n lo awn ọmọde lati mura bii agbalagba.
Ajirebi ni asa kikun ẹfun sori awọn ọmọde lati le da bi agbalagba pẹlu ewu lori tabuku isẹ tiata gbaa.
O ni awọn agbalagba wa nilẹ to yẹ ki wọn maa lo, amọ ti wọn ba mura fun ọmọde lati se bii agbalagba, se onitọun le sọrọ tawọn agbalagba yoo sọ ni.
O ni eyi gan lo n mu ki awọn ololufẹ ere tiata maa fa sẹyin nitori awọn oniruuru ọna ti ko tọ, ti wọn n gba se ere tiata lode oni.
“Caucus” tan ko jọ lagbo tiata n da wahala silẹ:
Agba alawada naa tun woye pe bi awọn osere tiata se n pin ara wọn lẹgbẹlẹgbẹ ati nigunnigun eyi ti wn n pe ni Caucus ko boju mu to.
O ni isẹ tiata ko fara mọ eleyi, to si jẹ pe oju kansoso ni wn ti n mu awọn elere ti wọn ba fẹ lo ninu sinima kan.
“Ti mo ba wo ere sinima kan, ti mo si ri awọn oju kan nibẹ, mo ti mọ ibi ti wọn ti se, ara oun to n ba isẹ wa jẹ niyẹn, ko si yẹ ko ri bẹẹ.
Tẹlẹ tẹlẹ, kaakiri ilẹ Yoruba ni wn ti n mu awn osere ti yoo kopa ninu sinima kan, amọ lode oni, agbegbe kọọkan ati adugbo kọọkan ni wọn ti n ko ara jọ lati se sinima.







