‘Muslim Muslim Ticket’ tí APC ṣekò ní ìtẹ́wọ́gbà - Kukah

Awọn to n se iwọde

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Bisọọbu tíjọ Aguda ni Sokoto, Mathew Hassan Kukah, ti ni bi APC ṣe fa oludije ipo Aarẹ ati igbakẹji Aarẹ lati inu ẹsin kannaa ni ko ni itẹwọgba.

Kukah ni eyi si le ṣe ifasẹyin si ibaṣepọ awọn ẹlẹsin ni orilẹede Naijiria.

Bisọọbu Kukah sisọ loju ọrọ naa lasiko ifọrọwerọ to se lori ẹrọ amohunmaworan kan lọjọbọ ọsẹ yii.

O ni pẹlu bi awuyeawuye ṣe n waye, ti awọn eeyan ti kede erongba wọn, ko yẹ ki ẹgbẹ oṣelu APC faye silẹ fun ariyanjiyan yii.

Asaaju ẹsin naa woye pe ko yẹ ki Tinubu yan igbakẹji rẹ, Kashim Shettima, toun naa jẹ Musulumi, dupo kristẹni.

“Emi ko ro pe awọn ẹlẹsin Kristẹni le fọwọ si bẹẹ, nitori gbogbo wọn mọ pe awọn Musulumi naa ko le gba ki Kristẹni meji jade lati dupo.”

“Fun emi gẹgẹ bi kristẹni, ko ni itẹwọgba sugbọn nkan ti ẹgbẹ APC fẹ ṣe niyẹn. Ti iponlogo ba bẹrẹ, a ri nkan ti awọn eeyan fẹ sọ lori ẹ.”

“Ibeere ti mo bi awọn ọrẹ mi to jẹ Musulumi, paapa awọn to wa lati ariwa orilẹede yii ni pe, ṣe awọn le gba lati ṣe bi awọn Kristẹni ṣe ṣe ni ọdun 1984 ati 1993.”

Àṣìyàn olórí lọ́dún 2023 léwu fún ọjọ́ ọ̀la Nàìjíríà - Obasanjo

aworan Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Olusegun Obasanjo Presidential Library

Aarẹ nigba kan ri lorilẹede Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo ti rọ awọn araalu lati yan awọn olori ti yoo mu ilọsiwaju ba orilẹede yii.

Obasanjo woye pe asiyan olori lewu lọpọlọpọ fun ọjọ ọla Naijiria.

Obasanjo ṣo eleyi nigba ti o kopa ninu ayẹyẹ ọdun kẹẹdogun ti ajọ alaanu Wilson Badejo Foundation to waye lọjọbọ ọsẹ yii, ni ipinlẹ Eko

Aarẹ tẹlẹ naa ṣekilọ pe afi ki awọn ọmọ Naijiria yan aarẹ ati awọn olori to ni ifẹ ilu, nitori ewu wa fun orilẹede yii ti asiyan olori tuntun ba waye.

“Afi ki a yan olori to ma ni ifẹ wa lọdun, nitori ti a ba ṣe bẹẹ, ireti wa pe ilọsiwaju maa wa fun wa”

“Ti a ko ba le yan olori gidi lọdun 2023, nkan buruku le sẹlẹ sugbọn a gba a ladura pe ki nkan buruku ma waye sugbọn a gbọdọ yan olori to nife ilu lọdun 2023.”

Aarẹ Obasanjo ni idi ti Naijiria ṣe kuna lati ni ilọsiwaju ni isẹ ati ati idunkoko awọn agbebọn to n waye loorekoore.

“Ọrẹ mi, Oloogbe Ahmed Loda ma n sọ fun mi pe, Ọlọrun fun orilẹede yii ni gbogbo nkan ti yoo wulo fun,.

O ni a ko nilo adura nitori ti Ọlọrun fun wa ni gbogbo nkan, amọ a n ṣe wọn balabala.

“Mo sọ fun pe pẹlu gbogbo iyẹn, a si lilo adura nitori nkan to dara, fẹ adura, idakeji naa nilo adura, fun idi eyi, a si lilo adura.”

Agbébọn da ìbọn bo ọkọ̀ mi, àmọ́ ẹ̀mí mi kò bọ́ - Cubana Chief Priest

Àtúnṣe gbọdọ̀ bá ilẹ̀ Igbo, ó tó gẹ́ẹ́ - Cubana Chief Priest

Aworan Chief Priest ati ọkọ rẹ ti wọn yinbọn lu

Oríṣun àwòrán, Instagram/cubana_chiefpriest

Gbajumọ ori ayelujara kan, Paschal Okechukwu ti ọpọ mọ si ''Cubana Chief Priest'' ti tan imọlẹ si iṣẹlẹ ikọlu tawọn agbebọn kan ti dabọn bo ọkọ rẹ.

Kaakiri oju ayelujara ni aworan ọkọ rẹ ti ọta ibọn ba yii wa.

Cubana Chief Priest ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye sugbọn ''ni ipinlẹ Anambra lo ti ṣẹlẹ, kii ṣe ni ipinlẹ Imo bawọn akọroyin kan ti ṣe sọ.''

O sọ pe nigba toun n lọ si Asaba ni ipinlẹ Delta lati Anambra ni iṣẹlẹ naa waye

Ninu ọrọ to fi soju opo rẹ ni Instagram, Cubana sọ lọjọ Aiku pe''Ọlọrun lo ṣe''

"Ootọ ibẹ ni pe a ni lati ṣe atunṣe gbogbo ilẹ Igbo''

Ọkọ Cubana ti ibọn bajẹ

Oríṣun àwòrán, cubana_chiefpriest/Instagram

Ninu fidio to gbode kaakiri ori ayelujara, n se ni wọn da ọta ibọn bo ọkọ rẹ.

Chief Priest sọ pe ko si eeyan kankan to ba iṣẹlẹ naa lọ tabi to farapa.

BBC gbiyanju lati ba ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ nipa iṣẹlẹ yii ṣugbọn alukoro wọn ko gbe ipe lori ago rẹ.

Bẹẹ naa ni alukoro ọlọpaa Tochukwu Ikenga ko fesi si atẹjisẹ taa fi sọwọ si lori ẹrọ alagbeka rẹ.

Aworan Cubana Chief Priest

Oríṣun àwòrán, CUBANA CHIEF PRIEST

Ta ni Cubana Chief Priest?

Paschal Chibuike Okechukwu ti ọpọ mọ si ''Cubana Chief Priest ni wn bi ni ọjọ Keji osu Kẹrin ọdun 1981 nilu Otsu nipinlẹ Imo.

Gbajumọ amuludun ni Cubana Chief Priest, to si ni awọn ibudo igbafẹ nilu Eko ati Abuja bii ile itura ati ile ounjẹ igbalode lorisirisi.

Olowo yalumọ nii se amọ ilu Eko lo fi se ibujoko, to si maa n se agbelarugẹ awn eeyan to ni ẹbun orin kikọ.

O di ilumọọka nigba to gbalejo gbajumọ akọrin takansufe nni, Davido ati afẹsọna rẹ, Chioma nile itura to n sakoso, ti olorin naa ti wa kọrin.

 Ọpọ eeyan lo peju sibi eto naa eyi to mu ki Cubana di gbajumọ nla.