Irọ́ ni wọ́n pa mọ́ mi, mi ò gbé Atiku lọ ilé ẹjọ́ – Wike

Oríṣun àwòrán, @aatiku
Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti sọ pe irọ ni awọn iroyin to lọ ni giboro pe oun ti gbe oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ati gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal, lọ ile ẹjọ.
Nigba to n sọrọ nibi ti wọn ti n ṣi ibugbe awọn oṣiṣẹ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa niluu Port Harcourt, Wike ni ohun to ṣe pataki lọwọ yii ni ọna ti oun yoo gba lati mu ki awọn eeyan ipinlẹ naa oun jẹ mudunmudun ijọba awarawa.
O ni “Awọn eeyan ti n pe mi lori aago pe mo gbe Atiku Abubakar lọ sile ẹjọ.”
“Mo fẹ sọ ni gbangba bayii pe mi o gbe Atiku lọ sile ẹjọ kankan o.”
“Mo fẹ ki awọn ọmọ Naijiria mọ, lootọ ni mi o sọ nnkankan, iṣẹ ti mo n ṣe ni lati jẹ ki awọn eeyan ipinlẹ mi adun ijọba awarawa.”
O tẹsiwaju pe “Ti wọn ba padanu ipo naa lẹyin eto idibo, ki ẹnikankan ma pe orukọ mi, mo ti sọ fun awọn oludije naa tẹlẹ.”
“Ti mo ba fẹ lọ sile ẹjọ, mo ti maa lọ sile ẹjọ laarin ọsẹ meji.”
“Agbo awọn oludije naa ni wọn ti n sọ awọn nnkan wọnyii, ẹ jẹ ki gbogbo aye gbọ o, wọn si ro pe wọn fẹ ba orukọ mi jẹ ni.”
“Ohun to yẹ ki a maa sọ bayii ni bi a sẹ maa jaweolubori ninu eto idibo to n bọ.
Ṣaaju ni iwe ẹjọ kan ti kọkọ gbode lori ayelujara, ninu eyii ti Wike ti pe Atiku ati Tambuwal lẹjọ lori esi ibo abẹle lati yan oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu idibo Aarẹ ọdun to n bọ.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Wike wọ́ Atiku àti Tambuwal lọ ilé ẹjọ́ lórí ìbò abẹ́nú PDP

Aawọ oselu to n waye ninu ẹgbẹ oselu PDP ti n gba ọna miran yọ, to si ti lọwọ ofin ninu plu.
Idi ni pe Gomina Nyesom Wike ti ipinlẹ Rivers, ti gbe oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, lọ sile ẹjọ.
Bakan naa ni Wike tun wọ Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal ati ẹgbẹ oṣelu PDP lọ ile ẹjọ.
Ẹjọ yii si lo da lori ipa ti wọn ko ninu eto idibo abẹnu to waye ni ọjọ kejidinlọgbọn ati kọkandinlọgbọn, oṣu karun un ọdun 2022.
Ninu iwe to fi ransẹ sile ẹjọ, ti nọmba idamọ rẹ jẹ FHC/ABJ/CS/782/2022, Wike pẹlu agba ọjẹ kan ninu PDP, Newgent Ekamon ni ki ile ẹjọ yii ibo abẹnu naa danu.
Ibo abẹnu naa si lo kede Abubakar Atiku bii oludije aarẹ fun ẹgbẹ oselu PDP.
Amọ Wike ti wa n rọ ile ẹjọ pe ko pasẹ fun ajọ INEC pe ko yọ orukọ Atiku kuro, ko si fi orukọ toun rọpo rẹ, gẹgẹ bi oludide sipo Aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP.
Nyesom Wike ati Newgent Ekamon ni wọn jẹ olupẹjọ ninu ẹjọ naa, nigba tawọn ọlujẹjọ si jẹ ajọ INEC, ẹgbẹ oṣelu PDP, AminuTambuwal ati Abubakar Atiku.
Wike salaye pe Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal ni ki awọn alatilẹyin oun dibo fun Atiku Abubakar lasiko eto idibo abẹnu naa.
O ni Tambuwal gbe igbesẹ naa lẹyin ti gbogbo awọn oludije ti kọkọ jade lati bawọn alatilẹyin wọn sọrọ.
Lẹyin idibo naa, O ni Atiku bori pẹlu ibo toto 371, ti oun si ni ibo 237 nigba ti Bukola Saraki ni ibo 70.
Idi si ree to fi ni alaga fun ẹgbẹ oṣelu naa, Iyorchia Ayu wa kede Gomina ipinlẹ Sokoto gẹgẹ bi akọni eto idibo abẹnu naa.
Awọn olupẹjọ naa tun fi ẹsun mẹjọ kan awọn olujẹjọ naa, ti wọn si ni awọn fẹ mọ boya Tambuwal ti padanu ibo rẹ lab ofin, lẹyin to kede pe oun ko dije du ipo naa mọ.
Wọn ni pe ko yẹ ki wọn da ibo Tambuwal ọhun mọ ti Atiku Abubakar niwọn igba to ti kede saaju pe oun ko dije mọ.
Awọn olupẹjọ naa wa rọ ile ẹjọ pe ko kede pe ki ẹgbẹ oṣelu PDP ma da ibo Tambuwal ati Atiku papọ, eyi ti yoo fun Wike ni anfani lati jẹ oludide sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu naa.
Wọn tun wa ni ki ile ẹjọ da awọn lare lori bi ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe kuna lati ṣe ohun to tọ, pẹlu bo se da ibo Atiku ati Tambuwal papọ.
"PDP ati Atiku lo anfani pe Tambuwal fẹ jawọ ninu eto idibo naa, ni wọn se fun Tambuwal ni anfani lati sọ fawọn alatilẹyin rẹ ni gbangba pe ki wọn dibo fun Atiku.

Oríṣun àwòrán, @aminuwaziritambuwa
Wike ati Ekamon wa ni ki ile ẹjọ pa a lasẹ fun ajọ INEC lati yọ orukọ Atiku Abubakar kuro gẹgẹ bi oludide sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.
“Ile ẹjọ ni lati pa lasẹ fun ajọ INEC pe ki wọn yọ orukọ Atiku Abubakar kuro ninu awọn to n dije sipo Aarẹ lọdun 2023.”
“Ẹgbẹ oṣelu PDP ni lati tun esi idibo to waye losu karun ka nitori pe o mẹhẹ.”
Newgent Ekamon wa ni ki ile ẹjọ kede Nyesom Wike gẹgẹ bi ẹni to bori ninu eto idibo abẹnu PDP, ko si di oludije sipo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ekamon ni gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, oun lẹ fọwọ gbaya pe Nyesom Wike lori bori ninu eto idibo abẹnu naa.
Mùsíọ́mù ìlú London ṣetán láti da ère ìṣẹ̀mbáyé 72 tí wọ́n jí kó ní Benin padà sí Naijiria

Oríṣun àwòrán, HORNIMAN MUSEUM
Awọn alaṣẹ Musiọmu kan niluu London ni awọn ti ṣetan lati da awọn ere iṣembaye ti wọn ji ko ni Naijiria pada.
Awọn ere iṣembaye naa ti wọn ji ko niluu Benin ni nnkan bii ọgọrun ọdun ṣeyin ni iye rẹ jẹ mejilelaadọrin.
Gẹgẹ bii ohun ti awọn alaṣẹ musiọmu Horniman sọ niluu London, wọn ni awọn yoo fi awọn ere ọhun ṣọwọ si ijọba Naijiri laipẹ.
Lara awọn nnkan ti wọn yoo da pada ni ere ‘brass’ mejila ati kọkọrọ kan ti wọn fi n ṣilẹkun ile ọba.

Oríṣun àwòrán, HORNIMAN MUSEUM
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti ijọba naijiria bere fun awọn ere naa pada loṣu Kinni ọdun yii.
Musiọmu ọhun, Hornima Musem, sọ pe oun ti jiroro pẹlu awọn ti ọrọ kan nilẹ Gẹẹsi ati ni Naijiria ki oun to be igbesẹ ọhun.
Alaga musiọmu naa, Eve Salomon, sọ pe “Ohun to tọ ati eyii to yẹ ni lati da awọn ere iṣẹmbaye ọhun pada si ibi ti wọn ti wa.”
Awọn n fẹ ki wọn da awọn ere ilẹ Afrika pada
Lati nnkan bii ọdun diẹ sẹyin lawọn eeyan kaakiri agbaye ti n ke si awọn ijọba nilẹ yuroopu lati da awọn ere ti wọn ji ko ni Afrika pada sile.
Lara awọn ere ti awọn eeyan ni ki wọn da pada ni eyii ti wọn ji ko niluu Benin.
Eve Salomon ni “O han gbangba pe pẹlu adigi ni wọn fi ko awọn ere wọnyi wa sibi, ohun to si yẹ gẹgẹ bii ọmoluabi fun wa ni ki a da wọn pada.”
“Awa gẹgẹ bii musiọmu Horniman, inu wa dun lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ajọ to n risi ọrọ musiọmu ni Najiria lati da awọn ere naa pada.”












