Kí ló mú kí Bàbá àti ọmọ kú sínú kàǹga lọ́jọ́ kan náà?
Ọmọ mẹ́ẹ̀dógún ni ìyàwó mẹ́ta bí fún bàbá agbẹ́kànga, tó sì fi wọn sílẹ̀ láì dágbére

Oríṣun àwòrán, SANI ABU
Titi aye ni ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 yoo ma jẹ ọjọ manigbagbe fun idile Mallam Bala Wudil tori bi eeyan meji ninu ẹbi rẹ meji se ku sinu kanga lọjọ kan naa.
Iṣẹ agbẹkanga ni Mallam Bala ati ọmọ rẹ, Sanusi n ṣe lagbebe Wudil, niluu Kano.
Gẹgẹ bii nnkan ti iyawo rẹ, Adama Bala sọ, ọkunrin ọhun ti n gbẹ kanga jẹun, o ti le lọdun marundinlogoji bayii, ki iṣẹlẹ laabi naa to ṣẹlẹ.
Adama ni “Laarọ ọjọ naa, a ji laarọ kutu, o ṣe ohun gbogbo to yẹ ka ṣe, o jẹ ounjẹ aarọ, o si sọ fun mi pe oun ni iṣẹ kan nile Alhaji, oun si ti ṣetan lati lọ.”
“Emi ati iyale mi gbadura fun ko to lọ, amọ mi o mọ pe igba ikẹyin ti mo maa ri niyẹn.”
Airi afẹfẹ mi sinu nisalẹ kanga lo sekupa baba ati ọmọ rẹ - Osisẹ Panapana
Ẹwẹ, ileesẹ panapana ni Kano sọ fun BBC pe nnkan bii ago mọkanla abọ Aarọ ni awọn gbọ pe awọn eeyan kan ha sinu kanga, awọn oṣiṣẹ awọn si lọ sibẹ lati doola awọn eeyan naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Saminu Yusuf ni lẹyin iṣẹju diẹ ti awọn de ibẹ, lawọn ba eeyan meji ninu kanga naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ko awọn eyan naa jade amọ awọn mejeji ti dakẹ.
Ileeṣẹ ọhun sọ pe airi eemi mi simu ni isalẹ kanga naa, lo mu ẹmi wọn lọ.
Iyawo oloogbe ọhun, amọ ti kii ṣe oun lo bi ọmọ to ku pẹlu oloogbe ṣalaye pe ọmọ mẹẹdogun ni Bala fi silẹ saye lọ.
O ni “Lapapọ, ọmọ mẹẹdogun lo ni, eyii ti iyale mi ati iyawo rẹ to ti doloogbe bi fun ṣaaju pẹlu ọmọ mẹrin ti mo bi fun.”
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye:
Alhaji Saleh Kausami to ni ile ti Bala ati ọmọ rẹ ku si yii, sọ fun BBC pe ibanujẹ nla ni iṣẹlẹ naa jẹ fun oun.
Kausani ṣalaye pe ọmọ oloogbe naa lo kọkọ wọ inu kanga naa, ki baba rẹ to tẹle.
O ni “Ohun to ṣẹlẹ ni pe ọmọ lo kọkọ wọ inu kanga ọhun ki baba rẹ ro tẹle lẹyin iṣẹju diẹ.
Ohun ti a ṣakiyesi ni pe o ṣoro fun awọn mejeji lati mi ninu kanga naa, ni a ṣe ke si ileeṣẹ panapana.”
“O to nnkan bii iṣẹju mẹẹdogun ki awọn panapana to de, amọ o ṣe ni laanu pe wọn ti dakẹ lasiko ti awọn panapana yoo fi yọ wọn ninu kanga ọhun.”:
Alhaji Saleh ni ile oloogbe naa ni oun wa lati ba wọn kẹdun lasiko to n jabọ iṣẹlẹ naa fun BBC.
















