Kò bá à jẹ́ Tinubu tàbí Obi, à ní kí ipò ààrẹ bọ́ sẹ́kún gúúsù ló jà jù - Akeredolu

aworan gomina ipinlẹ ondo

Oríṣun àwòrán, @rotimiaketi

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kede pe oun ko ti yii ipinu oun pada lori pe ki ipo Aarẹ bọ si ẹkun guusu Naijiria.

Akeredolu fi ọwọ idaniloju yii sọya nigba to sọrọ nibi ayẹyẹ iranti ọdun kan Ọjọgbọn Bankole Oke to waye ni fasiti ibadan lọjọbo.

Akeredolu ni yoo dara ki ipo agbara bọ si ẹkun guusu orilẹede yii, ti oun ko si kọ boya o bọ si ọwọ Peter Obi ti Labour Party tabi Bola Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC.

Akeredolu ni ilana ti wa lati ọdun 1999 pe agbara yoo maa yipo lati ẹkun ariwa si guusu Naijiria.

Amọ o ni o ba oun ninu jẹ pe awọn kan lati ẹkun ariwa si fẹ gba agbara lọwọ Aarẹ Buhari.

“Ti Peter Obi ba jẹ Aarẹ, o dara, ti Bola Ahmed Tinubu ba di Aarẹ, eyun naa dara, temi ni pe ki o jẹ pe a yan aarẹ tuntun lati ẹkun guusu orilẹede yii.”

Akeredolu wa rọ awọn ọmọ orilẹede yii lati mase jẹ ki agbara pada si ẹkun ariwa nitori pe yoo ba ilana to ti wa lati ọdun 1999 jẹ ni.

aworan gomina ipinlẹ ondo

Oríṣun àwòrán, @rotimiaketi

Ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá mú olùdíje ààrẹ lẹ́kùn àríwá kò nífẹ̀ẹ́ aráàlú - Akeredolu

Gomina Akeredolu wa tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ẹgbẹ oṣelu to ba mu oludije lati ẹkun ariwa lasiko yii ko nifẹ araalu rara.

O ni Peter Obi ni ẹtọ si ipo Aarẹ nitori pe lati ẹkun guusu lo ti wa.” 

“A ti ṣetan lati fi gbogbo nnkan ti a ni lati ri daju pe agbara wa si ẹkun guusu orilẹede yii.”

O salaye pe igbọraẹniye ti wa lati ọdun 1999 pe, ipo agbara yoo ma lọ yika laarin ẹkun guusu ati ariwa.

Sugbọn o ni awọn eeyan kan lo ni erongba lati yii atunto naa danu.

Akeredolu wa kesi awọn araalu lati yago fun irufẹ awọn eeyan naa nitori wọn n wa ohunkonu, papaa julọ ọrọ ẹsin lati fi tu Najiria ka.

“Awọn eeyan yii fẹ da orilẹede Naijiria ru ni pẹlu erongba wọn ti ko ba ojumu, ti wọn si n wa gbogbo ọna lati ripe wọn wa ni ipo agbara.

“A ko gbọdọ jẹ ki wọn fi ọrọ ẹsin tan wa, nitori kii ṣe ọrọ ẹsin lo kan, ninu gbogbo nnkan to n ba orilẹede yii finra.”