Àwọn tó ń fi àìsàn bú Tinubu ti lulẹ̀, ó dàgbà lóọ̀tọ́ọ́, àmọ́ kò ṣàìsàn - APC
Ọ̀pọ̀ àwọn adarí tó dáńtọ́ lágbàyéé ló ní àìsàn lára, kò sẹ́ni tó fi àrùn ara bú wọn - Keyamo

Oríṣun àwòrán, BATOfficial and video screenshot
Oriṣiriṣi awọn eeyan kaakiri Naijiria lo ti n sọ erongba wọn lori fidio kan to gba ori ayelujara kan.
Fidio naa lo safihan awọn ọmọ ẹgbẹ Pyrates Confraternity to n sọrọ kobakungbe nipa oludije sipo Aarẹ fẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu.
Ninu fidio ọhun ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa, ti wọn wọ aṣọ funfun ati pupa, ti n kọ orin pe:
“Ọwọ rẹ n gbọn, ẹṣẹ rẹ n gbọn, baba ti ara rẹ ko da, to n kọ orin pe oun lo kan.”
Ti ẹ ko ba gbagbe, aṣa “Emilokan” yii gbode lẹyin ti Bola Tinubu sọ ọrọ naa nibi ipade kan niluu Abeokuta lasiko to n sọ eredi ti awọn eeyan ṣe gbọdọ gbe oun de ipo Aarẹ.
Lẹyin ti fidio naa jade, ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu atẹ lu fidio ọhun pe ohun ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa ṣe ko bojumu to.
Lara awọn eeyan to tako orin naa ni agbaọjẹ onkọwe ni, ọjọgbọn Wole Soyinka, adari ẹgbẹ Pyrates Confraternity naa atawọn alẹnulọrọ mii ni Najjiria.
Ki ni Soyinka sọ?
Ninu atẹjade kan, Soyinka ni inu oun ko dun si iwa ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa hu.
O ni “Niwọn igba ti gbogbo aye ti mọ iha ti mo kọ si ẹgbẹ naa, mọ fẹ sọ ni gbangba pe emi ko faramọ ohun ti wọn ṣe, mi o si lọwọ si.”
“Gẹgẹ bii awọn ẹgbẹ mii, Pyrates Confraternity lafaani lati sọrọ bo ṣe wu wọn labẹ ofin.
Bẹẹ emi naa lagbara lati sọrọ labẹ ofin, mi o mọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ yii yoo ṣọ ọrọ ti wọn sọ yii si oludije naa.”
“Iṣẹlẹ naa jẹ eyii to ya mi lẹnu pupọ.”
Awọn adari Pyrates Confraternity naa sọrọ:
Agbẹnusọ ẹgbẹ Pyrates Confraternity, Abiola Owoaje ninu atẹjadde kan sọ pe awọn ko lọwọ si ohun ti awọn ọmọ awọn ṣe ninu fidio naa rara.
Pyrates ni ẹgbẹ naa kii da si ọrọ oṣelu.
Owoaje ni asiko ti awọn n ṣe ayẹyẹ ọdun mẹrindinlọgbọn ẹgbẹ ọhun ni isẹlẹ naa waye.
O ni “Gẹgẹ bii aṣa wa, a maa n kọ orin, ti a o si maa to lọwọwọ gẹgẹ bi a ti n ṣe lati ọdun mẹrindinlaadọta sẹyin.”
“Jẹjẹ wa ni a n kọ orin naa lọ ki fidio aburu yii to jade.”
“Tako nnkan to han ninu fidio ọhun, a kii ṣe ẹgbẹ oṣẹlu, ko si si ọkan lara awọn nnkan ti a n ṣe to lọwọ oṣelu ninu, bẹẹ ni ko si igba kankan ti a ti kọ orin oṣelu ninu ipade wa.”
Ire ni eebu Pyrates pada ja si Tinubu - Keyamo

Oríṣun àwòrán, @officialABAT
Ẹwẹ, agbẹnusọ fun ikọ ipolongo idibo Bola Tinubu, amofin Festus Keyamo, SAN, ti sọ pe ohun ti awọn eeyan naa ṣe lọwọ oṣelu ninu.
Amọ o ni ire ni eebu naa pada ja si fun Tinubu bo tilẹ jẹ pe ibi ni wọn n lepa si.
Keyamo lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba.
O ni lootọ ni Tinubu ti dagba, amọ ko ṣaisan, ati pe bo tilẹ n ṣaisan gan, aisan naa ko ni ko maa le tukọ Naijiria de ebute ogo.
Keyamo ni “Fun awọn ti ko mọ, diẹ lara awọn adari ati Aarẹ to lamilaaka julọ ninu itan, lo ni aisan kan tabi omiran lara.
Eyii ko si ni ki wọn ma ṣe iṣẹ wọn doju ami.”
‘To ba jẹ aisan ni wọn fi fẹ tabuku Tinubu, wọn ti lulẹ’
Agbẹnusọ fun ikọ to n seto ipolongo ibo fun Tinubu tun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC Yoruba.
O ni “Mi o sọ pe Tinubu n ṣaisan o, amọ to ba jẹ ọrọ aisan ni wọn fẹ fi tabuku Tinubu ni, wọn ti lulẹ.”
“Fun apẹrẹ, Franklin Delano Roosevelt to jẹ Aarẹ ilẹ Amẹrika kẹtalelọgbọn, ori ‘wheelchair’ lo wa.
Franklin si ṣiṣẹ to bẹẹ to fi jẹ ọkan lara awọn Aarẹ to ṣiṣẹ julọ l’Amẹrika.”
“Bakan naa ni John MacCain to du ipo Aarẹ pẹlu Brack Obama l’Amẹrika, apa kan n dun lẹyin to ṣeṣe loju ogun.
Obama ko fi apa naa bu rara, bẹẹ si ni McCain ko bu Obama, o yẹ ki awọn eeyan wa kọgbọn lara irufẹ awọn oloṣelu bẹẹ.”
Keyamo pari ọrọ rẹ pe “Tinubu koju oṣuwọn lati ṣe Aarẹ Naijiria, oun lo gbena woju Abacha lasiko ijọba ologun.
Oun yii kan naa lo gbena woju ẹgbẹ PDP ti ko jẹ ki Naijiria jẹ ẹlẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo, mo lero pe o yẹ ki awọn eeyan bọwọ fun Tinubu.”















