Wo àwọn nọ́mbà ìpè agbófinró tó yẹ kò mọ̀, èyí tó pè tí ìkọlù agbébọn bá dé

Àkọlé fídíò, Laa-Han-Mi: Fídíò rèé nípa ààbò tó mẹ́hẹ àti ọ̀nà tí aráàlú yóò fi dààbò bo ara wọn
Wo àwọn nọ́mbà ìpè agbófinró tó yẹ kò mọ̀, èyí tó pè tí ìkọlù agbébọn bá dé
Busayo James-Onifade, atọkun eto

Ọrọ eto aabo orilẹede yii ti di irawọ ọsan, eyi to ti n ba awọn agba ati ọmọde lẹru bayii.

Eyi ko si sẹyin bi awọn agbebọn se n pa ọpọlọpọ ọmọ orilẹede yii, ti wọn si n se aimọye eeyan miran lese nigba ti wọn tun n ba ọpọ dukia jẹ pẹlu.

Koda, ọrọ aabo to mẹhẹ naa ko yọ ẹkun kankan silẹ lorilẹede Naijiria, nitori bi awọn eeyan laabi yii se n pa ọpọ eeyan lẹkun ariwa, ni wọn tun n yabo awọn ibudo ipejọp eeyan lẹkun guusu Naijiria.

A si lee sọ wipe ko si ipinlẹ kankan lorilẹede Naijiria to fara rọ, igbe ẹ gba wa si ni ọpọ eeyan n pariwo kiri.

Bi a ko ba gbọ igbe lori ipaniyan, a gbọ igbe pe wọn ti ji awọn eeyan kan gbe lọ lati gba owo tabi pa wọn.

Idi ree ti BBC Yoruba fi se eto Laa-Han-Mi, to maa n waye lẹẹkọkan lori awn akanse isẹlẹ to ba se koko.

Ninu fidio eto naa ni akọroyin BBC Yoruba ti mẹnuba awọn isẹlẹ ipaniyan, ijinigbe ati biba dukia jẹ to n waye yika Naijiria.

A tun bojuwo awọn aayan ti ijọba n gbe lati pana eto aabo to mẹhẹ naa, eyi ti ko tii so eso rere

Bakan naa la tun bojuwo awọn igbesẹ to yẹ ki araalu gbe lati daabo bo ara wọn lọwọ awọn onisẹ iku yii.

Ẹ dẹkun irin alẹ - Onimọ nipa eto aabo:

Nibayi onimọ kan nipa eto aabo, to kopa lori eto Laa-Han-Mi, Olatunbosun Bolarinwa, ti wa gba awọn ọmọ Naijiria nimọran lati jawọ ninu irin oru tabl laajin.

O ni o yẹ ki wọn maa fi owe Yoruba kan to sọ pe ‘ẹni ba ba bii re, kii rin loru’ lati fi se ọrọ akọmọna wọn.

“Gbogbo faaji ki faaji ti eeyan ba ti n se nigboro, bi alẹ ba ti lẹ, o yẹ ka fi ọmọ ayo fun ayo, ki koowa si morile ile rẹ lọ sinmi.”

Onimọ nipa eto aabo naa wa rọ awọn araalu lati mọ nọmba ipe awọn agbofinro ti wọn le pe, lasiko ti ewu tabi ijamba ba wọle de.

Busayo James-Onifade, atọkun eto

Ẹ wo awọn nọmba ipe agbofinro to yẹ kẹ ni lọwọ, eyi tẹ le pe lasiko ewu:

  • Nomba 112 ti ijọba kede fun ipe pajawiri yika orilẹede, o ko si nilo owo lori foonu rẹ lati pe ipe yii
  • Fun awọn olugbe ipinlẹ Eko, ẹ tun le pe nọmba 727 fun ipe Pajawiri yatọ si 112 to wa fun gbogbo Naijiria
  • Nọmba ipe ọga ọlọpaa to n dari agọ ọlọpaa to ba sun mọ yin julọ (DPO)

Onimọ naa ni ta ba ti pe awọn nọmba ipe yii iranlọwọ yoo dide si wa, to si tun rọ wa lati maa fi oju sọri bii alakan ni gbogbo ayika ta ba de.