Ọwọ́ wa tẹ̀ bàbá onílé táwọn agbébọn gbé ilé rẹ̀ ní Owo saájú ìkọlù sí ṣọ̀ọ̀ṣì - Akeredolu
Àwọn agbébọn tọ kọlu ṣọ́ọ̀ṣì Owo ti dé gbaga wa - Iléeṣẹ́ ológun

Iroyin to n tẹ BBC lọwọ ni yajoyajo ti fidi rẹ mulẹ pe ọwọ ileesẹ ologun ti tẹ awọn agbebọn ti kọlu sọọsi kan ni Owo.
Olori awọn osisẹ alaabo nilẹ wa, Ọgagun Lucky Irabor lo sisọ loju isẹlẹ naa lasiko ton jẹwọ pẹlu awọn lọgalọga akọroyin.
Irabor ni kii se igi awọn ologun nikan lo da igbo se nidi ọrọ naa amọ awọn se aseyọri naa nifọwọkọwọ pẹlu awọn ileesẹ agbofinro yoku.
O ni ileesẹ ọlọpaa, ologun ati awọn ọtẹlẹmuyẹ DSS lo seranwọ lati mu awọn agbebọn naa.
Bẹẹ ba gbagbe, Olowo tilu Owo ti kede saaju fun awọn araalu rẹ pe ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn agbebọn to sisẹ ibi naa.
Amọ ileesẹ ọlọpaa kede nigba naa pe oun ko mọ ohunkohun nipa ohun ti Olowo sọ pe ọwọ ti tẹ awọn agbebọn naa.

Ọwọ́ ti tẹ̀ bàbá onílé táwọn agbébọn ń gbé ní Owo saájú ìkọlù - Akeredolu
Wayi o, Gpmina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti tun fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn agbebọn to wa kọlu sọọsi Owo.
Akeredolu sisọ loju ọrọ yii lasiko abẹwo alaga ẹgbẹ awọn akọroyin si ọọfisi rẹ.
Akeredolu ni bakan naa ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ baba onile ti awn agbebọn naa gbe ile rẹ saaju ikọlu naa.
O ni awọn agbofinro ko fi epo bọ iyọ lati se awari awọn agbebọn to sisẹ laabi nilu Owo naa.
Atẹjade kan ti akọwe gomina Akeredolu feto iroyin, Richard Olatunde fisita lo sisọ loju ọrọ yii lọsan ọjọ Isẹgun.
Akeredolu ni “Inu wa dun si olori ọmọ ogun alaabo to kede pe wọn ti mu awọn agbebọn naa.
A ti mọ tẹlẹ pe ọwọ ti tẹ awọn agbebọn naa lati ọjọ mta kan, a kan pinnu lati dakẹ lori rẹ ni.
Amọ a ti pinnu lati kede sita bayii lori rẹ, ti is si ti n lọ lọwọ lori iwadii nipa wọn, ta si tun ti n dọdẹ awọn agbebọn yoku to ti salọ.
Ki lo ti waye sẹyin?
Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ karun osu Kẹfa ọdun 2022 ni awọn agbebọn kan kọlu ijọ St Francis nilu Owo.
Lẹyin isẹlẹ naa, eeyan mẹtalelogoji lo jade laye, ti ọpọlọpọ miran si farapa.
Koda, ọpọ awọn eeyan to fi ara pa nibi isẹlẹ naa si wa nile iwosan, nibi ti wn ti n gba itọju.
















