Àwọn aya Yekeen Ajileye ló fa ìpinyà láàrin wa débi pé mo fẹ́ pa ara mi - Abija

Àkọlé fídíò, Abija: Babaláwo àti Ọdẹ ní mí, mo sì tún mú iṣẹ́ tíátà mọ
Àwọn aya Yekeen Ajileye ló fa ìpinyà láàrin wa débi pé mo fẹ́ pa ara mi - Abija
abija

Alhaji Tajudeen Oyewole, ti ọpọ eeyan mọ si Abija wara bí ẹkun, jẹ osere tiata to gbajumọ laarin ilu.

Ọpọlọpọ eeyan si lo maa n fẹ wo ere rẹ, paapaa, nitori ede Yoruba to yanranti ati ọfọ̀ to maa n pe, ti ko si ni fi ọkan pe meji.

BBC Yoruba wa gbajumọ osere tiata yi kan lati mọ nipa igbesi aye rẹ, awọn ipenija to koju rẹ ati ajọsepọ rẹ pẹlu ọga rẹ, Yekeen Ajileye to ti di oloogbe.

Awakọ ni mi, ilu Portharcourt ni mo n gbe, ki n to pade Ajileye:

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Abija ni oun ṣe iṣẹ́ to pọ gan, ọdẹ ni oun, babalawo sì ni oun pẹlu.

O ni baba to bi oun jẹ ọdẹ gidi ni, ti oun si tun jẹ babaláwo gidi.

Abija ni oun sa n yi gbogbo rẹ mọ ara wọn ni nitori nkan ti Ọlọrun ba ti kọ pe ọmọ o jẹ, ko si ẹnikẹ́ni to le yí padà.

Bakan naa lo fikun pe Awakọ gidi ni oun, oun kii si wa ọkọ kekere, awọn ọkọ nla ni oun maa n wa.

O ni nigba to ya, oun tẹle ẹ̀gbọ́n oun kan to ti di oloogbe lọ silu Portharcourt lati maa sisẹ nibẹ.

Portharcourt si ni Abija ti salaye oun pade Ọga oun, Alhaji Yekini Ajileye to wa si Port Harcourt wa ṣe ère orí ìtàgé.

‘Awọn ololufẹ mi fariga nigba ti Ajileye ni ki n gbé agbara fún atunbi, arole Abija’

Nigba to n sọrọ lori ere tiata to sọ di ilumọọka, Abija ni Ọ̀pá Aje ni Ọlọ́run lo fún awọn, tó si tun lo fún oun naa, inú Ọ̀pá Aje yìí ni Orúkọ Ábíjà si tí jáde.

 Bakan naa lo salaye pe ede aiyede bẹrẹ laarin oun ati Ajileye lasiko ti awọn n ya isẹ kan, to si ni kí olódi oun sọ pe oun ti wọlẹ.

 “Ajileye ni ki n sọ pe mo gbé agbara mi fún atunbi, tii se arole Abija nigbayen, sinima yí wa jáde amọ ko dun mọ awọn ololufẹ mi ninu.

 Awọn ololufẹ mi ni wọn wa pé mi pé ṣe wọn di mi loju ni, ki n to le yà sinima iru eleyi, mo ní wọn ko di mi loju, ibi Ọga ba ran lọ ní yóò lọ.

 Awọn ololufẹ mi gbe owo silẹ pe ki n fi gbe sinima mii sita, eyi ni mo fi kọ Ipadabọ Abija fun ara mi pe èmi ó kú ó, èmi ó re ibi kankan, n ko sì wọlẹ.”

Ọga mi fi Hajj dun mi, mo fẹ pa ara mi - Abija

Bakan naa ni Abija salaye nipa bi ipinya se waye laarin rẹ ati ọga rẹ nitori bi onitọun se kọ lati jẹ ko lọ sisẹ Hajj ni Mecca, to si gbe ipin rẹ fun ẹlomiran.

O ni awọn iyawo Alhaji Yekeen Ajileye lo ko si ninu, ti ko fi fun oun ni fọọmu hajj to yẹ ki oun lọ.

Abija fikun pe isẹlẹ naa dun oun de egungun, debi pe oun fẹ pokunso, ki oun si gba ẹmi ara oun.

O ni isẹlẹ naa ko itiju ati ẹsin ba oun, ti oun ko si le jade nile lasiko ti awọn yoku lọ sisẹ hajj naa.

Amọ o salaye pe lẹyin o rẹyin, Ọlọrun ran obinrin kan si oun, ti onitọun si pada ran oun lọ si Hajj naa, eyi to dun mọ oun ninu pupọ.