'Uncle' mi fi ipá bámi lòpọ̀ lọ́mọ ọdún 15, ó sì di oyún - Toyin Lawani

Àrùn jẹjẹrẹ bá ìdílé mi fínra, òun ló pa bàbá àti ìyá mi - Toyin Lawani

Toyin Lawani

Oríṣun àwòrán, toyinlawani_

Gbajugbaja oniṣowo, to tun jẹ oṣere tiata, Toyin Lawani ti ṣi aṣọ loju eegun nipa iriri rẹ lasiko to n dagba ati bi mọlẹbi rẹ kan ṣe fi ipa ba lopọ lọmọ ọdun mẹẹdogun.

Ninu ifrọwerọ kan lori eto “With Chude,” ni Lawani ti sọ pe aburo iya oun (uncle) lo fi ipa ba oun lopọ, ti ibalopọ naa si di oyun.

Yatọ si ibalopọ yii, Lawani tun sọrọ lori bi wọn ṣe maa n ni arun jẹjẹrẹ ninu idile wón.

Koda o ni arun naa lo mu ẹmi iya oun lọ lẹni ọdun mẹrindinlaaadọta, arun yii kan naa lo tun pa ababa rẹ.

Toyin Lawani

Oríṣun àwòrán, toyinlawani_

‘Uncle’ mi fi ipa bami lopọ nigba ti mo wa lọmọ ọdun marundinlogun

Lasiko ti atọkun eto naa, Chude Jideonwo bere bi igba ewe rẹ ṣe ri Lawani sọ pe ohun ti oju oun ri kii ṣe itan to wu oun lati maa sọ faraye.

O ni “Nigba ti mo wa lọmọ ọdun marundinlogun, ẹnikan fi ipa ba mi lopọ ladugbo wa, ọkan lara awọn abura iya mi si ni, o si ṣowo lati sọ ọrọ naa fun iya mi lọdun naa lọhun.”

“O jẹ ohun to bu omi tutu si mi lọkan pe iru nnkan bẹẹ n ṣẹlẹ si mi amọ mi o le sọrọ soke.”

Gẹgẹ bii ohun to sọ, lẹyin asiko ti ibalopọ naa di oyun ni oun tu aṣiri ọrọ naa fun ọkan lara awọn ẹgbọn iya oun obinrin ti orukọ rẹ n jẹ anti Bola, ti obinrin naa si mu oun lọ siluu Ibadan lati yọ oyun naa.

Lawani sọ pe asiko ti wọn n gbiyanjuu lati yọ oyun oṣu marun un ọhun ni oun wọ ile ẹkọ giga fasiti UNILAG to wa nilu Eko.

O ni ibi ti wọn ti n ṣe iforukọsilẹ awọn akẹkọọ tuntun ni ohun ti daku rọngbọndan.

Lẹyin ti iya rẹ wa ṣabẹwo si nile iwosan to wa ni dokita ṣalaye fun iya rẹ pe oun ti loyun amọ wọn ti yọ oyun naa.

Baba mi kọ mi lọmọ, mo korira iya mi

Amọ lẹyinorẹyin, Lawani sọ pe baba oun kọ oun lọmọ, oun si korira iya oun.

Eredi to ṣe korira iya rẹ, gẹgẹ bi ohun to sọ, ko ṣẹyin pe iya rẹ ọhun kii si nile lati ṣe itọju rẹ.

O ni “Mo korira iya mi gidi gan ni nitori kii si nile lati bojuto mi.”

“Gbogbo igba ni iya mi maa n rinrinajo... bii ko lọ si China loni tabi Hong Kong lọla, amọ o ṣẹṣẹ ye mi bayii ti emi naa ti di abiyamọ.”

Oniṣowo naa tun sọ pe oun ko le fi ẹnikẹni to ba jẹ ọkunrin ṣọ ọmọ oun nitori ohun ti oju oun ti ri ṣẹyin.

O ni “Mi o le fọkan tan ẹnikẹni, yala ẹgbọn tabi aburo obinri, ẹnikẹni lo le dalẹ rẹ.

Arun jẹjẹrẹ lo pa iya ati baba mi

Lasiko to n sọrọ lori ilera ara rẹ, Lawani sọ pe arun jẹjẹrẹ wa ninu idile wọn.

O ni “Baba mi kọmi lọmọ nigba ti mo wa lọmọ ọdun mẹrinla, iya ko kọ mi lọmọ amọ o tete jade laye lẹni ọdun mẹrindinlaadọta nitori arun jẹjẹrẹ.”

“Bakan naa arun jẹjẹrẹ lo pa baba mi.”

“Gẹgẹ bi mo ṣe sọ nipa baba ati iya mi, arun jẹjẹrẹ wa ninu ẹbi wa, mo nilo lati lọ maa ṣe ayẹwo ara mi loorekoore.”

Ṣọọbu mẹta ni mo ni si UNILAG nigba ti mo wa lọmọ ọdun mẹrindinlogun

Niti awọn aṣeyọri rẹ gẹgẹ bii oniṣowo, Lawani sọ pe bo tilẹ pe oju oun ri to nile aye, ti iya si jẹ oun, amọ oun ṣe aṣeyọri ninu owo ṣiṣẹ.

O ni “Ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni mo ti bẹrẹ aye mi, nigba naa lọhun, odidi ṣọọbu mẹta ọtọtọ ni mo ni si ọgba ile ẹkọ UNILAG.”

“Koda, ololufẹ mi atijọ to ro pe mi o ni le ṣe orire lai si oun, iyanlẹnu ni aṣeyọri mi jẹ fun bayii.”

Lawani pari ọrọ pe ohun to ṣe pataki si oun bayii ni bi oun yoo ṣe tọju awọn ọmọ oun ki oun si fi ogun ree silẹ fun wọn.

O ni “Mi o bikita ki n ku ni kekere, ọdun mẹrindinlaadọta pere ni iya mi lo laye ko to ku, ki wa ni temi?”