Àwọn èèyàn Ogbomoso faraya tóri ìjínigbé àti ìpànìyàn tó dógò tì wọ́n

Awọn oluwọde nilu Ogbomoso

Awọn eniyan ilu Ogbomoso tu jade lowurọ ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, lati ṣe iwọde tako awọn ijinigbe ati ipaniyan to n waye nilu naa.

Eyi waye lẹyin ti awọn agbebọn pa oniṣowo kan ati akẹkọọ fasiti Lautech kan ti wọn jigbe lọsẹ to kọja.

Ni nkan bi aago mẹsan-an owurọ ni iwọde wọrọwọ naa bẹrẹ ni agbagbe Taki, lopopona to lọ si Ilorin.

Ẹni to jẹ alaga igbimọ eleto aabo ilu Ogbomoso, igbakeji ọga agba ọlọpaa to ti fẹhinti, Shehu Babalola, sọ fun BBC pe awọn ṣe iwọde naa lati mase jẹ ki awọn ajinigbe ba ilu jẹ mọ awọn lori.

Ọgbẹni Babalola sọ pe awọn ijinigbe ati ipaniyan to n waye lati bi oṣu kan nilu naa, n dunkooko mọ alaafia ilu Ogbomoso.

Ẹ ma ti ọwọ oselu bọ ipenija eto aabo to n ba wa finra - Olamiju Akala

Ẹwẹ, oriṣiriṣi akọle ni awọn oluwọde naa gbe dani eyi ti wọn fi n kesi ijọba lati fi opin si eto aabo to mẹhẹ nilu naa.

Lẹyin ti wọn kuro ni Taki, ni wọn tun korajọ niwaju aafin Soun Ogbomoso to gbesẹ laipẹ.

Ẹnikan to ti fi igba kan jẹ aṣofin to ṣoju Ogbomoso nile aṣofin ipinlẹ Oyo, to tun jẹ ọmọ gomina ipinlẹ Oyo nigba kan, Olamiju Alao-Akala, to ba awọn oluwọde naa sọrọ, ni ninu ibanujẹ ni awọn korajọ pọ.

O ni oun bẹ awọn ọmọ ilu naa, lati ma fi ọrọ oṣelu bọ ipenija aabo to ti wọle tọ wọn, amọ ki wọn o fi imọ ṣọkan lati ṣẹgun.

Ọgbẹni Alao-Akala sọ pe araalu ni iṣẹ pupọ lati ṣe lori eto aabo, lati ran awọn eleto aabo lọwọ.

Akọle ti awọn oluwọde gbe dani

Ẹwẹ, minisita fun ọrọ ọdọ ati ere idaraya ni Naijiria, to si tun jẹ ọmọ bibi Ogbomoso, Sunday Dare, naa sọ pe ki awọn ọdọ ilu naa ma jẹ ki eti awọn oṣiṣẹ eleto aabo di ti wọn ba kofiri nkan ajeji kankan ninu ilu.

Ọgbẹni Dare, ti ẹnikan ṣoju fun sọ pe ki awọn ọdọ naa ma ṣe ohunkohun to le da igbesẹ ti awọn agbaagba ilu n gbe lori ipenija aabo to wọ ilu Ogbomoso.

'Irọ́ ni pé ọlọ́pàá mú ẹbí wa kan tó lọ́wọ́ nínú bí wọ́n se jí àti pa Gbenga àti akẹ́kọ̀ọ́ Lautech'

Ọgbẹni Gbenga Owolabi

Oríṣun àwòrán, Ayorinde Owolabi

Àkọlé àwòrán, Awọn ajinigbe pa Gbenga Owolabi ati Rachael Opadele lẹyin ti wọn gba miliọnu marun-un Naira lọwọ ẹbi wọn

Mọlẹbi oniṣowo ile itura kan ti awọn ajinigbe pa oun ati akẹkọọ fasiti Lautech lọsẹ to kọja ti sọ pe ayederu iroyin lo ni ọlọpaa ti mu aburo oloogbe to wa nidi iṣẹlẹ naa.

Ọsẹ to kọja ni awọn ajinigbe pa Ọgbẹni Gbenga Owolabi ati rachael Opadele, lẹ̀in ọjọ diẹ ni ahamọ.

Ọjọ Aiku ni iroyin jade si ori ayelujara pe ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Oyo tẹ ọkunrin kan to n jẹ Femi Owolabi, to lọwọ ninu bi wọn ṣe ji awọn eeyan naa gbe, ti wọn si tun pa wọn.

Ṣugbọn nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iroyin naa, ẹnikan to jẹ ẹgbọn oloogbe, Ọgbẹni Ayorinde Owolabi, sọ pe irọ patapata ni iroyin naa.

O ni awọn ko ni ẹnikẹni ninu ẹbi wọn gẹgẹ bi ẹgbọn tabi aburo, to n jẹ Femi Owolabi.

Bakan naa lo sọ pe ọlọpaa ko mu ẹnikẹni to jẹ ẹbi tabi ibatan wọn lori iṣẹlẹ naa.

Ọgbẹni Ayorinde sọ pe iroyin naa jẹ igbiyanju awọn eeyan kan, lati fọwọ bo otitọ iṣẹlẹ naa ni.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2022, ni awọn ajinigbe yawọ ile itura Gbenga Owolabi, ni agbagbe Abaa nilu Ogbomoso, ti wọn si ji oun ati oṣiṣẹ rẹ kan, Rachael Opadele gbe lọ.

Iroyin sọ pe laipẹ yii ni Owolabi de silu naa lati ilẹ America to fi ṣe ibugbe.

Bakan naa ni Rachael, jẹ akẹkọọ ni fasiti imọ ẹrọ Lautech, to lọ ṣiṣẹ nile itura naa, nitori iyanṣẹlodi ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, ASUU, to n lọ lọwọ.

Lẹyin ọjọ diẹ ni mọlẹbi Owolabi san miliọnu marun-un fun awọn ajinigbe naa, ṣugbọn pada pa awọn mejeeji lọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, lẹyin ti wọn gba owo tan.

Koda, iroyin sọ pe wọn tun pa ọlọkada to gbe ẹni to ko owo naa lọ.

Ẹni naa paapaa fi ara gba ọta ibọn, ko to raaye salọ.

Titi di asiko yii, ileeṣẹ ọlọpaa ko ti sọ boya o ti mu ẹnikẹni fun iṣẹlẹ naa.