Iléeṣẹ́ ológun kéde orúkọ àwọn afurasí agbébọn tó ṣé ìkọlù sì Owo

Ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun lorilẹede Naijiria, Lucky Irabor ti kede orukọ awọn afurasi agbebọn to se ikọlu si ile ijọsin aguda nilu Owo.
Ọjọ karun un oṣu kẹfa, ọdun 2022 ni isẹlẹ naa waye nibi ti eeyan mẹtalelogoji ti ku, ti eeyan to le ni aadọta si fara gbọgbẹ.
Irabor ka orukọ awọn afurasi naa nibi ipade akọroyin to waye lọọfisi ileesẹ ologun niluu Abuja.
Irabor ni pẹlu iranlọwọ ati atilẹyin awọn ẹsọ alaabo yoku, ọwọ tẹ awọn afurasi naa, ti orukọ wọn wa nisalẹ yii ati awọn ọsẹ miran ti wn tun se.
Orukọ awọn afurasi to sekupani ni Owo ti ọwọ ologun tẹ ree:
Idris AbdulMalik Omeiza: O tun se ikọlu si agọ ọlọpaa kan ni Kogi, to si ko eroja ijagun lọ
Oun lo lewaju ikọlu si ile jọsin Saint Francis Catholic Church ni Owo ati ikọlu si ileeṣẹ ọlọpaa kan ni ijọba ibilẹ Adavi nipinlẹ Kogi.
Ọjọ kẹtalelogun, ọsu kẹfa ọdun 2022 si ni isẹlẹ ti Kogi naa waye nibi ti wọn ti ṣekupa ọlọpaa kan, ti wọn si tun ji ọpọlọpọ ohun ija awọn ọlọpaa salọ.
Idris Abdulmalik Omeiza yii ni ọpọ eeyan tun mọ si Bin Malik.
Awọn eeyan yoku ti ọwọ tun tẹ pẹlu Omeiza ni Momoh Otohu Abubaker, ALIYU yusuf Itopa ati Auwal Ishaq Onimisi.
Idris Ojo: Ọmọ ẹgbẹ ISWAP to n gbaradi lati se ikọlu si agbegbe mii ti ọwọ fi tẹ ẹ
Idris Ojo jẹ ẹni ọdun mẹtalẹlọgbọn, ọmọ bibi ilu Ayetoro Osi ni ipinlẹ Ondo nii se.
Ojo ni ileesẹ ologun gbagbọ pe o jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP, to saa kuro ni ọgba ẹwọn Kuje lọjọ karun un oṣu kẹfa ọdun 2022.
Irabor ni ọwọ isinku awọn ọmọ ologun tẹ Ojo pẹlu ọkan lara awọn yoku rẹ.
“Idris Ojo pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ni wọn tun bẹrẹ si ni gbaradi lati ṣe ikọlu miiran si awọn agbegbe kan nigba ti ọwọ tẹ wọn.”
Jimoh Ibrahim:
Jimoh Ibrahim jẹ ẹni ọdun mọkandinlogoji, ti iwadi si fihan pe wọn ti n gbero lati ṣe ikọlu miiran si awọn agbegbe kan.
O wu mi ki n fi oju awọn afurasi yii han amọ mo fẹ ki iwadii pari lori wọn - Irabor
Ọga Agba ologun wa rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati ni igbagbọ ninu awọn ọmọ agbofinro nilẹ wa.
O fikun pe ki wọn mase bẹru siwaju eto idibo gbogbo ti yoo waye lọdun 2023.
O ni awọn ọmọ ologun ti bẹrẹ isẹ lati ri pe iwa iṣekupani ati ijinigbe di ohun igbagbe, ti ko si ni fi ibi kankan pa eto idibo lara lọdun 2023.
Bakan naa ni olori ileesẹ alaabo nilẹ wa salaye pe se ni ara oun n gbe kankan lati fi oju awọn afurasi agbebọn to kọlu ilu Owo sita.
Amọ o ni o nira lati se bẹẹ bayii ayafi ti iwadi ba ti pari lori wọn.
O wa fi da awọn ọmọ Naijiria loju wọn oun yoo fi oju awọn afurasi agbebọn naa han, ni kete ti iwadi ba ti pari.












