Ilé ti sú ọmọ mi torí ìdaṣẹ́sílẹ̀ ASUU ló ṣe lọ ṣiṣẹ́ nílé ìtura, tó fi pàdé ikú òjijì - Màmá Rachel Opadele
Olugbenga Owolabi: Opó ọlọ́kadà tó gbé owó lọ fún ajínigbé fi omíjé sọ ìgbà ìkẹyìn ọkọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Olugbenga Owolabi and Rachel Opadele
Adura nla ni pe ki ọba oke mase jẹ ka rin arinfẹsẹsi, ki iku ojiji ko ma se deede wa.\
Isẹlẹ ibanujẹ gbaa ni isẹlẹ to waye laipẹ yii nilu Ogbomoso lasiko ti awọn olubi ẹda kan se isẹ laabi nibẹ.’
Awọn agbebọn yii lo ya bo ile itura kan, ti wọn si ji onile itura naa gbe lọ pẹlu osisẹ rẹ kan to jẹ obinrin.
Orukọ onile itura naa ni Olugbenga Owolabi nigba ti orukọ osisẹ rẹ naa n jẹ Rachael Opadele.
Olugbenga Owolabi yii ni wọn lo fi ilu Amẹrika se ibujoko amọ to wa dale isẹ ile itura silẹ nilu abinibi rẹ, tii se Ogobomoso.
Gẹgẹ ba se gbọ, ko ju ọsẹ kan pere lọ to gunlẹ si Naijiria, ti awọn olubi ẹda naa kan kan fi wa ji gbe lọ pẹlu Rachel,tii se osisẹ ile itura naa.
Rachael yii si lo jẹ akẹkọ fasiti Lautech to jokoo sile nitori iyansẹlodi ẹgbẹ olukọ fasiti, ASUUU, to n lọ lọwọ.
Bakan naa ni awọn ajinigbe naa tun pa ọkunrin ọlọkada kan, Idowu, to fi ọkada rẹ gbe ẹni to gbe owo lọ fun awọn ajinigbe naa lowo ọhun ni ibuba wọn.
Ohun to wa se ni laanu ni bawọn agbebọn naa se gbẹmi Owolabi ati Rachel lẹyin ti wọn gba miliọnu marun naira tan lọwọ ẹbi Owolabi.
Isẹlẹ agbọsọgbanu yii lo mu ki BBC Yoruba de ilu Ogbomoso lati se abẹwo si ẹbi Rachel ati ọlọkada to ba isẹlẹ naa lọ pẹlu oniletura ọhun.
Ile ti su Rachel tori iyansẹlodi ASUU, lo se lọ n sisẹ nile itura – Mama Oloogbe:
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Grace Opadele, tii se mama ọmọbinrin to n sisẹ nile itura naa, salaye pe Racheal lo n pariwo pe ile ti su oun, lo se lọ sisẹ nile itura.
O ni ko ju bi osu kan to bẹrẹ isẹ nile itura naa, ti isẹlẹ ijinigbe ọhun fi waye.
Nigba to n sọ bo se la isẹlẹ ijinigbe naa kọja, Mama Rachel ni se ni wọn ni ki oun maa fi adura ran awọn lọwọ tori oniletura naa ni yoo san owo fawọn ajinigbe.
Amọ o ni lẹyin ọjọ melo kan ti isẹlẹ naa waye ni alufa ijọ oun wa tufọ iku ọmọ oun fun oun.
Ọkọ mi lo maa n sanwo ileẹkọ awọn ọmọ, bukata pọ niwaju wa – Iyawo Idowu Ọlọkada
Nigba toun naa n ba BBC Yoruba sọrọ, iyawo Idowu, tii se ọlọkada to gbe ẹni to lọ fun awọn ajinigbe naa ni miliọnu marun naira salaye pe ọkọ oun ko sọ ohun to n lọ se fun oun.
O ni lootọ ni Alaaba to jẹ olori abule naa maa n bẹ nisẹ loore koore, eyi si ni ko jẹ ki oun yari lọjọ naa pe ko ma jade lọwọ alẹ.
Obinrin naa ni bukata pọ niwaju awọn, to si jẹ pe ọkọ oun lo maa n san owo ẹkọ awọn ọmọ awọn.
O ni lootọ ni oun n sisẹ aserunlọsọ amọ oju mẹrin lo yẹ ko tọ ọmọ.







