Ẹ̀yin agbébọn, ẹ kúrò nílẹ̀ Yorùbá tàbí kẹ́ ẹ tún rí ìjà mí - Sunday Igboho

Ilẹ̀ Yorùbá ti ṣetán láti padà sí bí wọn ṣe wà tẹ́lẹ̀, kí òyìnbó tó dé - Sunday Igboho

aworan sunday igboho

Oríṣun àwòrán, @sunday_igboho1

Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, tii se asaaju ajijagbara fun ilẹ Yoruba, tun ti iransẹ ikilọ mii sawọn agbebọn to n ṣe ikọlu si ilẹ Yoruba.

Igboho ni yoo dara ki wọn tete pe yẹra kuro nilẹ Yoruba, ti wọn ko ba fẹ ri ogun.

Igboho sọ eleyi ninu atẹsita kan ti agbẹnusọ rẹ, Oluyomi Koiki, ka sita fun awọn akọroyin lọjọbọ ana.

Asaaju ajijagbara fun ilẹ Yoruba naa si pe akọle rẹ ni ‘’Awọn agbebọn ko le gba ilẹ Yoruba."

Ninu atẹsita naa ni Igboho ti sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti kuna lati fi opin si iṣekupani ati ijinigbe to wọpọ nilẹ Yoruba.

O ni ihuwasi awọn agbebọn ti jẹ ki ọpọlọpọ awọn ọmọ ilẹ Yoruba ni irẹwẹsi ọkan, ti pupọ wọn ko si ni igbagbọ mọ ninu orilẹede Naijiria.

Igboho tun wa fọwọ gbaya pe ominira ilẹ Yoruba nikan lo le mu opin si ipaniyan ati ijinigbe to wọpọ laarin wa.

O ni ilẹ Yoruba ti setan lati pada si bi wọn ṣe wa tẹlẹ, ki awọn oyinbo to de.

aworan sunday igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

‘N kò dẹ̀yìn lórí ìpinnú mi lórí òmìnira fún ilẹ̀ Yorùbá’

Asaaju ikọ ajijagbara Yoruba Nation naa tẹsiwaju pe “Ko si nkankan ti o jẹ mọ pe ma dẹyin lẹyin ipinnu mi lori ominira ile Yoruba.”

“A mọ pe iṣekupani ati ijinigbe ko jẹ awọn agbebọn yii loju, sugbọn o jẹ awa logun.

Idi niyẹn ti Aarẹ Muhammadu Buhari fi kọ lati gbe igbesẹ lori bi awọn agbebon ṣeṣe iku pa awọn eeyan wa.

Aarẹ ko ṣe nkankan rara.”

Sunday Igboho fikun pe “Yoruba fẹ gba ẹtọ rẹ gẹgẹ ba ṣe wa tẹlẹ ki awọn oyinbo to de si aarin wa.”

“Ẹtọ wa ni lati ọdọ Ọlọrun, a ko si ni yi ipinnu wa pada lori pe ominira ilẹ Yoruba ni a fẹ.”

“Mo wa rọ awọn agbebọn yii pe ki wọn yẹra fun wa nilẹ Yoruba, ti wọn ko ba fẹ ri ogun awọn alalẹ.”