Wo ohun mánigbàgbé tí yóò wáyé níbi ọdún Osun Osogbo lọdún yìí

Osun Osogbo Festival

Oríṣun àwòrán, Osun Osogbo Festival

Ayẹyẹ ọdun Osun osogbo ti ọdun yii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu bayii ni ipinlẹ osun, gbogbo awọn to si maa n kopa ninu ọdun naa kaakiri agbaye lo ti n tẹkọ leti lọ si Naijiria lati kopa ninu ọdun naa.

Ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ni ọdun Osun Osogbo ti ọdun 2022 bẹrẹ niluu Osogbo, to jẹ olu ilu ipinlẹ Osun.

Ọdun naa ni yoo wa sopin lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ yii kan naa.

Ọdọọdun ni ọdun Osun Osogbo maa n waye ninu oṣu Kẹjọ, lati bọ Osun, tii ṣe oriṣa to maa n fun awọn eeyan lọmọ.

Igbagbọ awọn to maa n ṣọdun naa ni pe ọdun Osun Osogbo tun wa lati tun adehun laarin awọn ẹda adarihurun ati awọn oriṣa ṣe.

Yatọ si pe o jẹ ọdun pataki fu awọn to n bọ Osun, o tun jẹ ọkan lara awọn ọdun to maa pe ọpọ ero, ti wọn jẹ arinrinajo afẹ wa siluu Osogbo kaakii agbaye.

Facebook/Osun Osogbo Festival

Oríṣun àwòrán, Osun Osogbo Festival

Lara awọn eto ti yoo waye nibi ọdun Osun Osogbo tọdun yii ree

Akọkọ ni fifọ Osun mọ ni ilana ibilẹ, eyii ti wọn n pe ni ‘Iwopopo’ to maa n waye lọjọ kinni, oṣu Kẹjọ.

Lẹyin naa ni titan atupa oloju mẹrindinlogun lẹyin ọjọ kẹta ti wọn ba ṣe Iwopopo tan.

Atupa oloju mẹrindinlogun yii ni igbagbọ wa pe o ti wa lati nnkan bii ẹẹdẹgbẹta ọdun sẹyin.

Ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ ni yoo kan eto “Bibọ Ade Ọba Osogbo,” eyii to jẹ ayajọ ọjọ ti wọn maa n fi ṣe ayẹsi awọn ọba to ti rewalẹ aṣa l’Osun.

To ba di ọjọbọ, ọjọ kọkanla oṣu Kẹjọ, wọn yoo da ifa arugba, nibi ti Arugba, iyẹn omidan ti ko ti mọ ọkunrin ri, yoo ti ṣe awọn etutu kan si awọn alalẹ.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ yii ni gbogbo ayẹyẹ ọdun naa yoo wa si ipari pẹlu bibọ “Osun Ajigun.”

Atupa olohu merindinlogun

Oríṣun àwòrán, Osun Osogbo Festival

Bi ọdun Osun Osogbo ṣe bẹrẹ

O ti le ni ẹẹdẹgbẹrin ọdun ti wọn ti n ṣe ọdun Osun Osogbo.

Gẹgẹ bii ohun ti a ka ninu itan, awọn aṣatipo kan, ti ogboju ọdẹ Olutimehin ko sodi lo lọ sidi odo Osun lọna ati bọ lọwọ iyan.

Nigba ti wọn de eti odo naa, Yeye Osun jade si wọn lati inu odo ọhun, o si ni ki Olutimehin ko awọn eeyan naa lọ sibi pataki kan, eyii ti a mọ lonii gẹgẹ bii ilu Osogbo.

Yeye osun ṣeleri lati daabo bo awọn eeyan naa, o si tun ṣeleri pe oun yoo maa pese fun ti wọn ba le maa ṣe iranti oun lọdọdun.

Awọn eeyan ọhun gba si Yeye Osun lẹnu lati maa bọ lọdọdun.

Anfani ọdun Osun Osogbo nipinlẹ Osun

Lakọkọ, ọdun naa jẹ ọkan lara awọn ọdun to maa gbe ọpọ ero kaakiri agbaye lọ si ipinlẹ osun, eyii to maa n ran ipinlẹ naa lọwọ lati fi aṣa abalaye rẹ han awọn alejo naa.

Ọdun naa tun jẹ asiko ti gbogbo awọn eeyan Osun maa n korajọ pọ ṣokan lai fi ti ẹya, ẹsin tabi ẹgbẹ oṣelu ṣe.

Ọdun Osun Osogbo tun maa n mu ki eto ọrọ aje ipinlẹ Osun burẹkẹ si pẹlu oniruru awọn eeyan to maa n wa kopa ninu ọdun ọhun.