N kó ní gbà káwọn ọ̀tá ìpínlẹ̀ Oyo ṣé àṣeyọrí – Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti ni oun ko ni gba fun awọn ọta ipinlẹ Oyo lati ṣe aseyọri ninu erongba wọn lati da alaafia ipinlẹ naa ru.
Makinde sọ eleyii nibi ayẹyẹ ọdun tuntun awọn musulumi, Hijrah 1444, to waye nile ijọba Ipinlẹ Oyo niluu Ibadan.
O ni oun mọ pe awọn ọdaran kan, ti wọn jẹ ọta ilu, fẹ da alaafia to n jọba ni ipinlẹ Oyo ru sugbọn oun ti setan lati ba wọn wi.
“Ijọba mi ti leke awọn ọdaran atawọn ọta ilu tipẹ, ti mo si tun ti ṣetan lati mase jẹ ki wọn ṣe aseyọri pẹlu erongba wọn.”
“Awọn ọta ilu ni awọn ti wọn ko fẹ ki a ni ilọsiwaju ni ipinlẹ wa.”
“Gbogbo wọn ni a ri pe a ba wọn wi pẹlu ida ofin, ti a ko si ni wo boya wọn jẹ eeyan pataki ni awujọ wa.”
Makinde wa fi da awọn olugbe ipinlẹ Oyo loju pe ijọba oun ti setan lati ri pe eto aabo ni ipinlẹ Oyo ni ọpọlọpọ atunṣe.
Bakan naa lo ni ilana atunse ọhun ko ni fun awọn ọta ilu naa lanfani lati da erupẹ si alaafia to wa nilu.
“A maa tubọ ṣe igbinyanju wa lati ri pe eto aabo ipinlẹ Oyo ko mẹyẹ.”
Ṣó tán! Àwọn ohun tí mo sọ pé yóò ṣelẹ̀, tẹ fi yọ mí nípò, ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí - Sanusi
N kó kàbámọ̀, n kó si ní dẹkùn láti sọ̀rọ̀ lórí ipò tí Nàìjíríà wà - Lamido

Oríṣun àwòrán, others
Emir ìlu Kano nigba kan, Sanusi Lamido Sanusi ti ni oun ko ni dẹkun lati sọ ohun to yẹ lati mu atunto ba orilẹede Naijiria.
Sanusi, ẹni to jẹ Khalifah fun ijọ Tijaniyat lorilẹede Naijiria ṣo eleyi, nigba ti o darapọ mọ ijọ naa ni bi ere itage kan ti o dale e lori niluu Abuja.
Akọle ere itage naa ni “Emir Sanusi: Truth in Time”.
Nigba to n sọrọ nibi eto naa, Emir Sanusi ni oun ni ohun to tọ lati ṣe afikun si idagbasoke Naijiria nitori oun ni iriri to peye ati pe oun ti sin ilu fun ọjọ pipẹ.
Sanusi wa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun bi ko ṣe fi ikan gba kan lọwọ rẹ.
“Mo ro pe Ọlọrun ko gba nkankan lọwọ mi, fun idi iyi, mi o kabamọ.”
“Mo ti pe ọmọ ọdun mọkanlelọgọta lọdun to kọja, mo si ti gun akasọ lati osisẹ banki, ti mo fi Aarẹ fun apapọ banki lorilẹede Naijiria.”
“Mo jẹ Emir ti Kano fun ọdun mẹfa, mo tun ti wa di Khalifah ti ijọ Tijaniyat.”
“Ti n ba ni mo ni ibajẹ ọkan, a jẹ pe mi o mọ oore Ọlọrun nitori pe eeyan melo lo ni anfani lati gun awọn akasọ yii.”
“Mọlẹbi mi ti n sin orilẹede Naijiria tipẹ, lati ori awọn baba baba mi.”
“Gbogbo wọn ni wọn kopa, ti wọn si fi ẹmi wọn silẹ lati mu itẹsiwaju ba orilẹede yi”

Oríṣun àwòrán, others
Mo setan lati fi ipo silẹ fun igbagbọ mi - Sanusi
“Mọlẹbi mi o ni dẹkun lati fi tọkantọkun mu atunto ba orilẹede wa, nitori ki ṣe orilẹede ẹnikan, ti gbogbo wa ni.”
O wa ni ti oun ba ni anfani lati mu ọkan larin ipo oun ati igbagbọ oun, Sanusi ni ohun faramọ pe ki oun di igbagbọ oun mu ju ipo lọ.
“Mo setan lati fi ipo silẹ fun igbagbọ mi.”
“Itan ni ọga adajọ ni ọjọkọjọ, gbogbo nkan ti mo sọ pe yoo sẹlẹ ti wọn fi yọ mi nipo, ni o ti sẹlẹ.”
“Fun idi eyi, Mi o kabamọ, mi o si ni dẹkun lati sọrọ lori orilẹede Najiria.”















