Àwa adarí tiraka láti mú ìbáṣepọ̀ àláfíà bá Nàíjíríà àmọ́ ìyapa ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣèdíwọ́ - IBB

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Babangida
Aarẹ ologun nigba kan ri, ajagunfẹhinti Ibrahim Babangida ti bu ẹnu atẹlu bi Naijria ṣe kọ lati di orilẹede lẹyin ọdun mọkanlelọgọta ta ti gba ominira.
Babangida woye ọrọ yii nigba ti ẹgbẹ kan to n ri si iṣọkan Naijiria ṣe abẹwo si lọjọ Aje ni ile rẹ to wa niluu Minna ni ipinlẹ Niger.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn to lanfani lati dari orilẹede yii gbiyanju lati mu ki ibaṣepọ alafia jọba nibi ti araalu yoo ti jẹ akọkọ.
Amọ o ni iyapa ẹya ati ẹsin n ba orilẹede yii ja .
“A kan gbiyanju lati di orilẹede ni, a ko tii jẹ orilẹede sibẹsibẹ, sugbọn nkan gidi ni bawọn eeyan bi yin ṣe n gbiyanju pe ki orilẹede yii si wa papọ.”
“Mo ro pe nkan to ti pẹ ni, mo ma a n sọ fun awọn ọrẹ mi, ẹgbọn mi ati awọn alabaṣe mi nipa orilẹede.
Sugbọn lẹyin ọdun mọkanlelọgọta, a sin sọrọ nipa bi asa, ẹsin ati ẹya se n di ilọsiwaju oriléede yii lọwọ.”
“Igbimọ yii ti bẹrẹ nkan gidi, ti mo si fẹ kin yin ku orire bi ẹ ṣe wa lati ẹya ati ẹsin ọtọtọ, lotitọ ẹyin gan ni ọmọ orilẹede Naijiria totọ.
Babangida wa ni fun idi eyi , oun setan lati gbaruku ti awọn ẹgbẹ naa, ki awọn ileri wọn le wa si imusẹ.















