Ó ṣeéṣe kí Salman Rushdie pàdánù ojú kàn nítorí ọ̀bẹ tí wọ́n gún un lọ́rùn - Abẹnusọ

aworan Salman Rushdie

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbajumọ onkọwe, Salman Rushdie, ni igbagbọ wa pe o ṣeṣe ki o padanu oju rẹ kan, ti o si le ma le sọrọ mọ lẹyin ikọlu to waye, ti ọkunrin kan ti kọlu lori itage, ti o si gun lọbẹ ni ọrun l'Amẹrika.

Onkọwe Rushdie, tii se ẹni ọdun marundinlọgọrin, ni agbẹnusọ re, Andrew Wylie gba ẹnu rẹ sọrọ fun awọn akọroyin niluu New York lorilẹede Amẹrika.

O ni pe iroyin lori bi ilera onkowe naa ṣe wa ni ko dara rara.

“O ṣeṣe ki Salman padanu oju rẹ kan, inira wa nibi apa re pẹlu ati pe ẹdọ rẹ ti bajẹ.”

“Salman le ma le sọrọ mọ lẹyin ikọlu naa.”

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ko ti le sọ pato ikan to fa iwa ti arakunrin naa wu sugbọn iwadi ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa

Ọlọpaa ni iwadi awọn fihan pe awọn osisẹ ati awọn oluworan gbinyanju lati mu aṣekupani oun silẹ de awọn ọlọpaa lati mu lọ si agọ wọn, ti ọkan lara awọn oluworan to jẹ dokita si ti kọkọ fun Onkowe naa ni awọn itọju, ki wọn to gbe lo si ile wosan.

Akọroyin to wa pẹlu Onkowe Rushdie, Henry Reese, fi ori rẹ gbalẹ, ti oun si wa ni ile wosan bayii.

Linda Abrams, ẹni to wa nibi iṣẹlẹ naa ni aṣekupani kọ lati dẹyin Onkowe Rushdie lẹyin ti awọn ti mu balẹ.

“O to ọkunrin mẹrin to mu aṣekupani naa balẹ sugbọn o si gbinyanju lati gun Onkowe na ni ọbẹ.”

Linda Abrams, an onlooker from the city of Buffalo, told The New York Times that the assailant kept trying to attack Mr Rushdie after he was restrained.

Ọkùnrin kan gún Salman Rushdie, òǹkọ̀wé ‘Satanic Verses’ lọ́bẹ ní ọrùn l‘Ámẹ́ríkà

Salman Rushdie

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbajumọ onkọwe nni, Salman Rushdie, tawọn mususlumi kan ti n dunkoko iku mọ nitori iwe rẹ, Satanic Verses to kọ, ni ọkunrin kan ti kọlu lori itage.

 Ilu York state lorilẹede Amẹrika ni isẹlẹ naa ti waye.

 Onkọwe naa, tii se ẹni ọdun marundinlọgọrin lo n sọrọ lọwọ nibi eto kan nile ẹkọ Chautauequa nigba ti isẹlẹ naa waye.

 Ileesẹ ọlọpaa nilu New York salaye pe afurasi ọkunrin kan lo sare lọ sori pepele ti Rushdie ti n sọrọ, to si kọlu pẹlu ẹni to n fi ọrọ wa onkọwe naa lẹnu wo.

 "Rushdie ti gba ọgbẹ to lagbara ni ọrun” Eyi ni esi ti ọlọpaa sọ.

Ọkọ ofurufu kekere ni wọn fi gbe Rushdie lọ sile iwosan abẹle kan amọ ko sẹni to le sọ iru ipo to wa lọwọlọwọ.

Bakan naa ni ẹni to n fi ọrọ wa onkọwe naa lẹnu wo, Henry Reese, tun ni ọgbẹ kekere kan ni ori.

Reese ni oludasilẹ keji ninu ajọ kan ti ko wa lati pawo wọle, to n pese aabo fawọn onkọwe to ba sa si abẹ rẹ nitori idunkoko iku.

Ibi ti Rushdie ti farapa pọ diẹ

Dokita kan to wa nibi eto ti wọn ti ṣe ikọlu si Rushdie sọ fun ileeṣẹ iroyin New York Times pe oun bawọn tọju Rushdie lẹyin ti wọn gun lọbẹ.

O ni o farapa koda wọn gun lọbẹ lẹgbẹ ọtun ọrun rẹ.

O fikun pe niṣe ni ẹjẹ pọ labẹ rẹ lori pẹpẹlẹ ti wọn gbe si.

''Awọn eeyan n sọ pe o ṣi n mi lọwọ, o ṣi n mi lọwọ''

Gẹgẹ bi ọrọ ti ileeṣẹ iroyin Reuters lawọn gbọ lẹnu aṣoju Rushdie, wọn ṣe iṣẹ abẹ fun lọwọ.

Andrew Wylie to jẹ aṣoju akọwe yi ni lootọ ni wọn n ṣe iṣẹ abẹ fun un.

Ọkọ ofurufu ti wọn fi n gbe Rushdie lọ sile iwosan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ileeṣẹ ọlọpaa lawọn mu eeyan kan nibi iṣẹlẹ naa

Iroyin taa tun gbọ ni pe ileeṣẹ ọlọpaa lawọn ti mu afurasi kan nibi iṣẹlẹ naa.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita, wọn fidi ọrọ mulẹ pe lootọ ni Rushdie fara gbọgbẹ lọrun rẹ ti wọn si ti fi baalu ayarafo ẹlikọpta gbe lọ si ileewosan kan ni itoosi.

Wọn fi kun pe awọn ko le sọ pato ipo to wa bayi.

Àkọlé fídíò, Salman Rushdie: The moments after author was attacked

Aṣọ dudu ni ẹni to gun lọbẹ wọ

Akọroyin ileeṣẹ iroyin Buffalo,Mark Sommer wa ni kalẹ to si ti n ba awọn oṣoju mi koro sọrọ.

O jabọ fun ileeṣẹ iroyin BBC pe ẹni to ṣe ikọlu si Rushdie jade laarin awọn ero to wa nibi ipagọ naa to si wọ iboju dudu ko to bẹs ori itage to ti ṣe ikọlu sii Rushdie.

Ko pẹ si igba naa awọn eeyan bi mẹwaa si mẹẹdogun ṣuru bo ti wọn si gba Rushdie la lọwọ rẹ.

Rushdie ṣe diẹ nilẹẹlẹ kawọn eeyan naa to gbe dide to sirin kuro lori itage.

Ko pẹ sigba naa ni wọn fi baalu aba sibi yowu ẹlikọpta gbe kuro.

Sommer sọ pe lọpọ igba Rushdie a maa rin pẹlu awọn ẹṣọ to pọ.

''O ṣoro diẹ lati gbọ pe ko ni awọn ẹsọ alaabo to peye lẹgbẹ''