Wo bí tọkọtaya ṣe fi ìmọ̀ ìṣìrò jẹ tẹ́tẹ́ $26m àti ìdíje oríire míì l‘Amẹrika

Aworan Jerry ati iyawo rẹ Marge

Oríṣun àwòrán, Jerry Selbee

Ti ẹlomiran yoo fi jade laye, yoo maa bawọn ta tẹtẹ ni, kọbọ to n dan bayi, ko ni ri nibẹ.

Ayanmọ kaluku ọtọọtọ ṣugbọn ni ti tawọn tọkọtaya kan ni orilẹede Amẹrika, igba ti wọn fẹyinti nidi iṣẹ tan ni wọn jẹ obitibiti owo nidi tẹtẹ.

Ọna wo ni wọn gbe gba, ki si ni aṣiri ti wọn lo lati fi jẹ owo to wọ miliọnu mẹrindinlọgbọn dọla laarin ọdun 2003 si 2012?

Jerry ati Marge Selbee lorukọ wọn, itan taa si fẹ mu tọ yinwa yii yoo ṣalaye bi wọn ṣe lo imọ iṣiro, fi jẹ aimọye miliọnu dọla nidi tẹtẹ Lotto.

"Ere idaraya tẹtẹ tita ta gbiyanju rẹ wo, lo mu wa ja soju ọna oriire"

Ige aye ti ko mu wahala wa ni Jerry ati Selbee n gbe ni ilu Evart ni Michigan.

Ọmọ mẹfa ni wọn bi ti wọn si ni ṣọọbu kekere kan ti wọn ti n ta nkan elo.

Ninu sọọbu naa, Jerry lo n mojuto ọti tita nigba ti iyawo rẹ a si maa ta siga nibẹ.

Lẹyin ọpọ ọdun ti wọn ṣiṣẹ tara wọn, ni Jerry ati iyawo rẹ Selbee ni o to gẹ-awọn fẹ fẹyinti nidi iṣẹ.

Asiko isinmi yii ni wọn ja si ere idaraya onitẹtẹ tuntun kan to jade, ti Jerry si ni ki oun gbiyanju lati kopa ninu rẹ.

''Iṣẹju mẹta pere lo gba mi lati mọ aṣiri tẹtẹ yii''

Ibeere kan ti ọpọ n beere ni pe bawo lawọn mejeeji to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ yii, ṣe mọ aṣiri to wa nidi tẹtẹ debi pe wọn jẹ aimọye dọla nidi rẹ?

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan, awọn tọkọtaya yii sọ ni ṣoki pe awọn lo oje kan ti ko tako ofin tẹtẹ tita, o si jẹ bi idan fun awọn.

Ki wa ni aṣiri yi iati fọmula ti wọn lawọn lo pẹlu?

Iṣiro ni wọn sọ pe awọn lo, to si jẹ bi idan fawọn.

Ajẹ bi idan ''sure banker'' nọmba ja si Jerry lọwọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igba akọkọ ti Jerry foju sunukun wo ere tẹtẹ yi, lo ti ri awọn kudiẹ kudiẹ kan eleyi to ri pe ti oun ba lo oje to mọgbọn wa, aṣeyọri ni yoo ja si.

"Lẹyin ti mo ka nipa ere idaraya tẹtẹ yi ninu iwe iroyin, mo ri pe anfaani nla leleyi jẹ.

Lati le jẹ owo nidi tẹtẹ yii, eeyan ni lati jẹ nọmba mẹfa nibẹ''

O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ lasiko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin CBC ni ọdun 2019 pe:

''Bi eeyan kankan ko ba gba nọmaba mẹfẹẹfa, wọn yoo pin laarin awọn to gba marun un ninu rẹ, mẹrin tabi mẹta''

Jerry sọ pe oun ri pe bi oun ba le ra tikẹẹti tẹtẹ to pọ, oun yoo lanfaani lati le jẹ owo nibẹ.

O ṣe isiro pe bi oun ba na bi ẹgbẹrun kan dọla le diẹ lori tikẹẹti kan, oun yoo lanfaani lati jẹ o kere tan tikẹẹti mẹrin.

"Mo jẹ ẹgbẹrun kan dọla lẹyin ti mo jẹ tikẹẹti mẹrin yii,ti mo si jẹ nọmba mejidinlogun ti iye owo wọn wọ aadọta dọla.

Lapapọ iye ti mo jẹ si jẹ nkan bi $900.

Bi mo ba pa eleyi papọ mọ $1,000 ti mo kọkọ jẹ, yoo jẹ $1,900.

Iṣiro ti ko le rara ni. Bi mo ba fi nkan bi $1,100 sinu tẹtẹ yii, nkan bi $1,900 ni mo maa jẹ pada.''

Wọn ti sọ igbesi aye Jerry ati Iyawo rẹ di fiimu

Aworan lati inu sinima igbe aye Jerry ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, PARAMOUNT +

Aworan sinima igbe aye Jerry ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, PARAMOUNT +

Bi ere bi ere Jerry ati iyawo rẹ ba bẹrẹ si ni ta awọn tẹtẹ lorisi titi ti wọn fi jẹ owo to to miliọnu mẹrindinlọgbọn dọla.

Ọrọ yi ru ọpọ loju ti awọn akọroyin lorisi si n pe wọn sori eto lati wa sọ ọna ti wọn gbe gba.

Ka to wi ka to fọ, wọn ti gbe fiimu kan jade nipa igbe aye awọn mejeeji ati ọna ti wọn fi lo isiro maths lati jẹ obitibiti owo nigba arugbo wọn.