Aráàlú, ẹ nàka sáwọn agbébọn tó pa ọlọ́pàá, wọn kò ní lọ láìjìyà – Buhari

Aarẹ oril.ẹede yii, Muhammadu Buhari ti n tara poro lori ikọlu awọn agbebọn si agọ ọlọpaa nipinlẹ Imo.
Buhari wa n leri leka pe ti asọ ba fi si loju eegun nipa awọn osika ẹda naa, wọn yoo jẹ iyan wn nisu.
Atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ fun aarẹ Buhari, Garba Shehu fisita lo salaye bẹẹ eyi ti aarẹ fi n sọ ero rẹ nipa bawọn eeyan kan se pa ọlpaa mẹrin, ti wọn si bẹ araalu mẹfa lori nipinlẹ Imo.
Aarẹ Buhari ni isẹlẹ naa ba ni ninujẹ pupọ, ti ko si jẹ itẹwọgba pẹlu afikun pe ijọba oun yoo gbe igbesẹ to yẹ lati se iwadi awọn osika ẹda to huwa ibi ọhun.
“Mo wa n rọ awọn asaaju ẹsin ati awujọ lati maa sọrọ sita lati tako awọn iwa isekupani to n di lemọlemọ yii.
Bakan naa ni mo n rọ wọn lati maa daabo bo awọn asa ajogunba wa nidi ẹsin ati asa.
Gbogbo awọn to ba si mọ awọn eeyan to sisẹ ibi yii ni mo n rọ lati tu asiri wọn sita, ka le fi kele ofin gbe wọn.”
Aarẹ orilẹede yii wa ba awọn mọlẹbi awọn agbofinro to di oloogbe ọhun kẹdun, to fi mọ ijọba orilẹede Niger, ti wọn bẹ ori awọn ọmọ ilẹ naa nipinlẹ Imo.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ki lo sẹlẹ ni ipinlẹ Imo:
Awọn olọpaa mẹrin ti pade iku ojiji latari bi awọn afurasi agbebọn kan ṣe ṣe ikọlu si ileesẹ ọlọpaa to wa Agwa ni ijọba ibilẹ Oguta ni ipinlẹ Imo, ti wọn si tun dana sun pupọ lara awọn ọkọ ileesẹ olopaa naa.
Awọn agbebọn naa ni wọn dana sun meji lara awọn ọlọpaa ọhun, ti wọn si fi ibọn pa meji yoku.
Isẹlẹ yii lo waye lẹyin ti awọn afurasi agbegbọn naa ti kọkọ ṣe ikọlu si arakunrin kan, ti wọn si pa oun ati iyawo re ki wọn to fẹṣẹ fẹẹ.
Osojumikoro sọ fun BBC Igbo pe ni dede ago mẹwa si mọkanla alẹ ni awọn afurasi agbegbọn naa ya wọ adugbo wọn pẹlu ọkọ ayokẹlẹ mẹta.
“Wọn wa pẹlu ọkọ akoyanrin ati ọkọ Sienna, wọn si sina ibọn bolẹ, gbogbo wa sare wọ ninu ile wa.”
“Nigbati ilẹ mọ ni agbọ pe wọn ti ṣe ikọlu si ileesẹ ọlọpaa, ti wọn si pa eeyan mẹrin pẹlu”.
Osojumikoro miiran to ba awọn akọroyin sọrọ nipe ijọba ni lati dide iranlọwọ nitori pe pupọ lara awọn ni awọn gbe pẹlu ibẹru, ti ọpọ si ti sa kuro ninu ilu latari bi ikọlu naa ṣe n waya loorekoore.
“Eyi ko ye wa mọ o, afi ki ọlọrun wa saaanu wa, nkan ti bajẹ jina.”
“Wọn dan obinrin ọlọpaa meji, ti wọn si fi ibọn pa awọn meji yoku to jẹ okunrin.”
“A o mọ boya wọn fẹ ki a sa kuro ni agbegbe wa ni o.”
Ẹlomiran to ba iko awọn akọroyin sọrọ ni, ọkan lara awọn ọlọpaa ni o jẹ ọmọkere ti wọn sẹsẹ gba si enu isẹ.”
“Ko ti pe ọsẹ meji to darapọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa na.”
Agbẹnusọ ileeṣe ọlọpaa ipinlẹ Imo, Micheal Abattam ti a kan si ni a ko tii ni anfani lati ba sọrọ lati fi idi isẹlẹ yii mulẹ.















