Irun imú mí jẹ ìwúrí, torí náà ni mo se ń bùgá káàkiri -Shyja,obìnrin tó ní irun imú bí ọkùnrin

Oríṣun àwòrán, Shyja
Bi ere bi ere ni irunmu arabinrin Shyja bẹrẹ si ni wu ni nkan bi ọdun marun un sẹyin.
Lati igba naa titi di asiko yi si lo ti jẹ ohun idunnu fun to si ti n da irunmu si bi ti ọkunrin.
Ẹni ọdun marundinlogoji ọmọ India yi lawọn eeyan kan ti n bẹnu atẹ lu tawọn mii si n gbori yin fun bakan naa loju opo ayelujara.
Agbegbe Kannur ni Guusu Kerala ni Shyja n gbe.
Ọpọ a maa beere lọwọ rẹ bi wọn ba ri aworan rẹ ni Facebook pe ki lo de to fi n da irunmu si bi ti ọkunrin?
Esi ti o si maa n fọ pada ni pe ''Ko si nkan ti mo le sọ ju pe mo nifẹ si i ni''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi awọn obinrin mii, irun bẹrẹ si ni foju han loju Shyja fun ọpọ ọdun.
Loore koore lo maa n fa irun ipenpeju rẹ to ba fẹ pọju.
Ni gbogbo igba yi, Shyja sọ pe ko jẹ oun logun lati fa irunimu to n ṣuyọ.
''Mi o le ro pe mo le ṣe ki n ma ni irun imu yi.Nigba ti ajakalẹ Covid-19 bẹrẹ, mi o nifẹ si wiwọ ibomu nitori o maa n bo oju mi''
Ọpọ eeyan lo gba nimoran pe ko fa irunmu rẹ kuro ṣugbọn Shyja kọ jalẹ.
''Mi o rẹwa nitori pe mo ni irunmu tabi mi o ni.Lọkan mi , mi o lerope mo rẹwa nigba kan ri ju bi mo ṣe wa nisinyi lọ''
Lawujọ awọn eeyan a maa gba awọn obinrin nimọran lati fa iru to ba hu loju wọn kuro ati pe ki wọn si san owo lọdọ awọn aṣaraloge lati le fi fa awọn irun yi.
Owo iyebiye lawọn eeyan n pa lagbaye nipasẹ tita awọn eronja fifa irun ara bi abẹ, ipara ati awọn mii fawọn obinrin to ba lowo lati ra wọn.
Lọdun 2016, arabinrin Harnaam Kaur to jẹ olupolongo nini ifẹ si ara ẹni wọ akọsilẹ iwe itan Guiness World Records gẹgẹ bi obinrin to kere julọ lagbaye to ni irungbọn to kun fọfọ.
Amọ lẹnu lọọlọ yi, awọn obinrin kan ti n fariga ti wọn si ti n da irun oju wọn si yala irunmu tabi irungbọn.
Ninu awọn ifọrọwanilẹnuwo to ṣe , o maa n saba sọrọ nipa bi gbigba kadara nipa irun oju rẹ ti ṣe jẹ ọna kan gbogi lati nifẹ ara rẹ to si tun jẹ ko bori awọn to n dẹyẹ si .












