Ọmọ Nàíjíríà yarí torí Joshua Dariye tó fẹ́ dupò lẹ́yìn tó tẹ̀wọ̀n dé

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ajọ kan to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, ti bu ẹnu atẹ lu iroyin kan to n ja nilẹ pe gomina ana ni ipinlẹ Plateau, Joshua Dariye, fẹ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Labour Party.
Dariye ni wọn lo gbe igbesẹ naa lati dije dupo sẹnẹtọ ni aarin gbungbun ipinlẹ Plateau lọdun 2023.
Dariye ni oun ati gomina tẹlẹ nipinlẹ Taraba, Jolly Nyame, sẹsẹ gba itusilẹ kuro ni ọgba ẹwọn.
Ile iṣẹ ọgba ẹwọn Naijiria lo kede itusilẹ wọn lẹyin ti wọn ti lo to ọdun mẹrin nibẹ.
Ti Buhari ba dari jin Dariye to ko owo araalu, Awọn ọmọ Naijiria ko le dari jin-in - Ajọ TI
Ajọ Transparency International wa rọ awọn ọmọ Naijiria la ti maṣe fun gomina tẹlẹ ri naa ni anfani lati jade dupo kankan nitori pe o sẹsẹ kuro ni ọgba ẹwọn ni.
Auwal Musa Rafsanjani, aṣoju ajọ naa ni, ti Dariye ba fi ni anfani lati pada sidi oṣelu, o ti fihan pe ọwọ yeperẹ ni a fi mu iwa jẹgudujẹra.
“Ti Aarẹ Buhari ba dari jin awọn tẹlẹ naa, awọn eeyan ilu ti wọn ko owo ti wọn jiya fun, ko darinji wọn rara.”
O ni ti idajọ ododo ati otitọ ba wa ni Naijiria, Dariye ko ti ẹ gbọdọ ni erongba pe oun fẹ jade dupo fun ipo kankan, lẹyin awọn nnkan to ti se ṣẹyin.
“Dariye to sọ pe ara oun ko ya, to fi kuro ni ọgba ẹwọn, wa fẹ lọ ṣe aṣoju ilu ni ile igbimọ aṣofin. Irọ ni wọn pa fun wa.”
A ko mọ boya Dariye si le ra tikẹti lati dije - Labour Party
Akọwe ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Dr Yunusa Tanko, ba BBC sọrọ, to si fi idi ọrọ naa mulẹ.
O ni awọn kan ke si ẹgbẹ oṣelu pe ṣe Dariye le ni anfani lati jade dupo sugbọn awọn ko mọ boya gomina ana naa si le ni anfani lati ra tikẹti ti yoo fi jide.
Pẹlu gbogbo awuyeawuye naa, gomina tẹlẹ naa ni ko ti jade lati sọrọ lori erongba rẹ
Fayose padà dé lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ lokè òkun, ẹbí àti ọ̀rẹ́ ki káàbọ̀

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka/Facebook
Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri, Ayodele Fayose ti pada si orilẹede Naijiria lẹyin to lọ oke okun fun isẹ abẹ.
Aburo rẹ, Ọmọba Isaac Fayose pẹlu agbẹnusọ rẹ rẹ, Lere Olayinka si ti ransẹ ikini kaabọ si gomina ana naa.
Agbẹnusọ Fayose, Lere Olayinka lo kede pe iṣẹ abẹ naa waye nitori bo ṣe farapa lẹyin ikọlu ti awọn kan ṣe si lasiko eto idibo ọdun 2018.
Nigba ti o wa ransẹ ikini kabọ si gomina naa lori ero ayelujara Facebook rẹ, Olayinka se afihan idunnu rẹ si ipadabọ Fayose si orilẹede Naijiria han.
Bakan naa lo se asadankata si lori awọn iwa akinkanju to ni o hu nigbati ti o wa ni ile wosan.
“Ewu ina ki pa awodi, kaabọ pada si orilẹede Naijaira, Osokomọlẹ Ẹkun oke.”

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka/Facebook
Bakana naa ni aburo gomina nigba kan ri naa, Isaac Fayose, ni ẹgbọn oun wu oun lori pupọ tori ipadabọ rẹ lẹyin isẹ abẹ ni oke okun.
“Awọn akọsẹmọsẹ le ṣe ohunkohun ṣugbọn wọn ko ni agbara lati yi ọjọ ọla pada.
“Ma jẹ ki wọn sọ pe o ko le di nkan ti o ba di, nitori pe wọn le sọ ọla.
“Osoko ni Osoko yio ma jẹ lọjọkọjọ.
“Inu mi dun si ẹgbọn mi, kaabọ pada si ile.”

Oríṣun àwòrán, isaacfayoseoriginal_/Instagram















