Ìjọba àpapọ̀ kò lè yá owó láti fi òpin sí ìyanṣẹ́lódì ASUU - Festus Keyamo

Oríṣun àwòrán, others
Minisita abẹle fun ọrọ osiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Festus Keyamo ti ni o kuna fun ijọba apapọ lati lọ ya owo lati fi opin si iyansẹlodi ti ajọ ẹgbẹ awọn oṣisẹ fasiti ni Naijiria, ASUU gun le.
Keyamo sọ eleyi nigba ti o sóró lori tẹlifisan Channels TV lanaa.
“Ṣe ka lọ ya owo lati san triliọnu kan naira lọdọọdun ni?
“A ko le fi aye gba ẹka kan lati fi ọgbọn ijapa mu wa lati lọ ya owo to to 1.2 trilionu nigbati owo ti a n ri lọdun gan jẹ triliọnu mefa. A ni ọna lati ṣe, ile wọsan lati kọ, ati ohun miiran lati ṣe.”
Minisita naa wa rọ awọn obi lati bẹ ajọ ẹgbẹ awọn oṣisẹ fasiti ni Naijiria, ASUU lati fi opin si iyansẹlodi naa.
O ni koda oun lee kunlẹ fun wọn ki wọn lee fopin si iyanṣẹlodi naa.

Oríṣun àwòrán, others
“Gẹgẹ bi Aarẹ ṣe ti ṣe, ẹni to ba mọ awọn ajọ ASUU, ko bẹ wọn lati ro ti awọn akẹẹko wọn.”
“Ẹ jẹ ki wọn pada si kilasi. Awọn ni kan kọ lo wa ni lorilẹede Naijiria. Awọn ni kan kọ ni gbe ọkan le ijọba apapọ fun owo. Ijọba apapọ ko ni ya owo lati tẹ ajọ ASUU lọrun.”
"O ye ko ye iwọnba awọn Kristẹni to n ja fun "Muslim-Muslim Ticket"

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọgbẹni Festus Keyamo mẹnu ba ọrọ bi oṣelu ṣe n lọ lọwọlọwọ ni Naijiria paapaa bi awọn kan ṣe yari lori igbesẹ oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC lati fi Musulumi ẹgbẹ rẹ ṣe igbakeji.
Festus ni nkan ti ko ye ọpọ Naijiria to n pariwo lori ọrọ yii ni pe wọn o ki n fi ẹsin ṣe oṣelu asiko si ti to fun wọn lati mọ bẹẹ.
"Ohun to ṣe pataki ni pe ọna ti ẹgbẹ yoo ṣe jawe olubori lo ṣe pataki ninu oṣelu, Tunubu ati Shettima yii si ni yoo fa Naijiria yọ kuro ninu oko iparun ti awn eeyan ni o n wọ lọ yii".
O ni ko si ẹni ti yoo lee sọ pe ko si iyatọ ni Naijiria lẹyin ọdun mẹrin ti Tinubu ati Shettima ba jawe olubori.
ASUU fi ọ̀sẹ̀ mẹ́rin kún ìyaṣẹ́lódì wọn bẹ̀rẹ̀ láti òní

Oríṣun àwòrán, @KAFTAN_TV
Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ni Naijiria, ASUU, ti ṣe afikun iye ọjọ iyanṣẹlodi wọn to n lọ lọwọ pẹlu ọsẹ mẹrin mii.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke sọ ninu atẹjade kan lọjọ Aje pe awọn gbe igbesẹ naa lati fun ijọba apapọ laa ye lati yanju awọn kudiẹ-kudiẹ to ni pẹlu awọn olukọ naa.
O ni igbesẹ ọhun waye lẹyin ipade pajawiri kan ti ẹgbẹ naa ṣe ni fasiti ilu Abuja lọjọ Aiku.
Afikun iye ọjọ iyansẹlodi naa yoo gberasọ lọjọ Aje, ọjọ kinni, oṣu Kejọ, ọdun 2022 yii.
Atẹjade naa ni “Lẹyin oniruru ijiroro atawọn ikuna ijọba lati mu ileri rẹ ṣẹ gẹgẹ bii ileri to ṣe lọ dun 2020, awọn adari ẹgbẹ yii ti pinnu lati sun iyaṣẹlodi wa siwaju pẹlu ọsẹ mẹrin mii lati oru ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ.”
Ijọba ko mu ọrọ rẹ ṣẹ lati ọdun 2009
Gẹgẹ bii ohun ti ASUU sọ, ede aiyede awọn ati ijọba apapọ ko ṣeyin awọn ajẹmọnu kan, to fi mọ ọrọ owo oṣu ati iṣakoso awọn fasiti, paapaa ni bi ijọba ṣe kọ lati mu awọn ileri rẹ kan ṣẹ lati ọdun 2009.
Atẹjade ọhun tẹsiwaju pe ṣaaju ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti kọkọ paṣẹ ki minisita eto ẹkọ yanju ọrọ naa ki wọn si jabọ fun oun laarin ọsẹ meji pere, amọ ohun iyalẹnu lo jẹ pe oṣu marun un lẹyin aṣẹ yii, bakan naa ṣi ni ọrọ ri.
ASUU ni “Awọn adari ASUU mọ riri iwọde ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC ati ẹgbẹ ajafẹtọ, CSO, ṣe lati ṣatilẹyin fun ASUU.”
ASUU wa sọ pe awọn ko ni gba ki ijọba lo arekereke kankan lati doju ikanni UTAS fun owo oṣu wọn bolẹ.
Lẹyin naa ni wọn ni awọn mọ pe awọn isọro kan ti ijọba n dojukọ lẹnu ọjọ mẹta yii amọ awọn ko gba ko ni gba ko gbe ọrọ ti sẹgbẹ kan.












