Òkú ọlọ́pàá tí àwọn ṣọ́jà pa pẹ̀lú ìbọn rẹ̀ ṣì wà pẹ̀lú wọn, wọn kò tíì gbé e fún wa -iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko

Olopaa

Oríṣun àwòrán, Lagos Police Command

Awọn ṣọja lati ọwọ kọkanlelọgọrin ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, 81 Division ti lu ọọlpaa kan pa lagbegbe Ọọ nipinlẹ Eko.

Igbakeji alukoro ileeṣẹ ọmọogun fun ọwọ kọkanlelọgọrin ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, 81 Division, Ọlaniyi Ọọba fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lọjọ Ẹti.

“awọn alaṣẹ ọwọ kọkanlelọgọrin ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, 81 Division ti n forikori pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lori ọrọ yii.

Iṣẹlẹ to bani ninujẹ pupọ ni iṣẹlẹ naa pẹlu bi o ṣe jẹ pe awọn alaṣẹ ọwọ ileeṣẹ ọmọogun naa ṣe koro oju si iwa kotọ gbogbo.”

Ifikunlukun ti bẹrẹ laarin ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ Naijiria lori iṣẹlẹ naa

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fi idi rẹ mulẹ pe ifikuluku ti waye laarin awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọmọogun ọwọ kọkanlelọgọrin ati kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko lori ọrọ naa.

Ninu aworan to fi si opo twitter rẹ, SP Benjamin Hundeyin ṣalaye pe ikọ kan lati ọwọ kọkanlelọgọrin ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, 81 Division ti lọ ki kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Abiọdun Alabi lori iku ọlọpaa ti awọn ṣọja kan lati ọwọ ileeṣẹ ọmọogun naa kọlu ti wọn si gbẹmi rẹ.

O ni awọn ọgagun agba KN Nwoko, ML Abubakar ati IE Akpaumontia lo ko ikọ naa sodi lọ ṣe abẹwo ibanikẹdun naa lọjọ Ẹti.

Ọgagun Ọlaniyi Ọṣọba sọ pe ọwọ kọkanlelọgọrin ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, 81 Division “ti gbe igbimọ oluwadi kalẹ lati wo iṣẹlẹ naa lẹyin eyi ti wọn yoo fi ijiya to ba tọ jẹ ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ naa ba ṣi mọ lori.”

Isipẹtọ Orukpe Monday

Oríṣun àwòrán, Lagos state police command

Àwọn sọ́jà lu ọlọ́pàá kan pa ní Eko

Ọkunrin ọlọpaa kan ti ku, lẹyin ti awọn sọja lu oun ati akẹgbẹ rẹ kan nipinlẹ Eko l’Ọjọbọ.

Iroyin sọ pe awọn sọja naa n kọja lọ ninu ọkọ bọọsi nla kan to gbe wọn loju ọna marosẹ Eko si Badagry, ti wọn si ha sinu sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ.

Diẹ lara awọn sọja naa sọkalẹ, ti wọn si fi ẹsẹ rin de ikorita kan nibi ti awọn ọlọpaa ti n dari lilọ bibọ ọkọ.

Ikorita ọhun ni iroyin sọ pe wọn ti lu awọn ọlọpaa naa ni alubami, wọn ko ibọn wọn, wọn si tun gbe awọn mejeeji lọ.

A gbọ pe awọn sọja naa to ọgbọn niye, ti gbogbo wọn si wa ni eto ẹkọsẹ kan nibudo ologun kan nipinlẹ Eko.

Awọn ọlọpaa meji ti wọn gbe lọ pada di eero ileewosan. Nibi ti wọn ti n gba itọju si ni Isipẹtọ Orukpe Monday, ti ku nitori ọgbẹ to ni lati ara iya ti awọn sọja fi jẹ ẹ.

Ẹnikeji ṣi wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin sọ fun BBC Pidgin pe awọn ti n jiroro pẹlu ileeṣẹ ologun lati yanju ọrọ naa.

Bakan naa lo ni awọn ti fi iroyin iku ọlọpaa naa to mọlẹbi rẹ leti ati pe awọn ọga ileeṣẹ ologun ti lọ ṣe abẹwo ibanikẹdun si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ileeṣẹ ologun tiẹ sọ ninu atẹjade kan pe lootọ ni iṣẹlẹ kan waye laarin awọn sọja rẹ ati awọn ọlọpaa nipinlẹ Eko, to si yọri si iku ọlọpaa kan.

Ninu atẹjade naa, agbẹnusọ fun ọ̀wọ́ kọkanlelọgọrin ileeṣẹ ologun, Olaniyi Osoba, sọ pe awọn kabamọ iṣẹlẹ naa, ati pe iwadii ti n lọ lọwọ.

O ni iya to tọ ni wọn o fi jẹ ẹnikẹni ti iwadii ba fihan pe o lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.