A gbà fún ìgbà àkọ́kọ́ pé à máa ń dúnàdúrà pẹ̀lú agbébọn - Iléeṣẹ́ ààrẹ

Awọn agbebọn ati ero reluwe

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ileeṣẹ aarẹ lorilẹede Naijiria sọ pe awọn agbebọn to kọlu reluwe Abuja si Kaduna, ti wọn si ji ọpọ ero ko, lo tan oun jẹ.

Ìjọba ni awọn agbebọn naa ni ko mu adehun wọn sẹ lẹyin ti oun mu adehun gbogbo ṣẹ tan lori ohun ti wọn beere fun lasiko idunadura lati tu awọn ti wọn ji gbe ninu reluwe silẹ.

‘Igba akọkọ ree ta kede pe a n dunadura pẹlu agbebọn tori wọn maa n yẹ adehun aarin wa’

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ aarẹ, Garba Shehu lo ṣalaye fun BBC pe ijọba gba lati tu iyawo olori awọn agbebọn naa to loyun silẹ.

Sugbọn se ni wọn tun gbe ibeere miran yọ.

Igba akọkọ kọ niyi ti awọn agbebọn naa ti n yẹ adehun wọn ṣugbọn igba akọkọ niyi ti ijọba yoo maa fi ẹnu ara rẹ sọ ọ jade pe idunadura n lọ laarin oun ati awọn agbesunmọmi ni Naijiria.

Nigba wo ni ikọlu si reluwe gan waye?

Buhari n bọ awọn eeyan to bọ lọwọ ajinigbe

Oríṣun àwòrán, State House Abuja

Ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2022 ni awọn agbebọn kọlu ọkọ oju irin to n na Abuja si Kaduna.

Ibọn ati oniruuru ohun ija oloro ni wọn fi lọ kọlu reluwe naa.

Lọpọ igba lawọn agbebọn naa ti maa n jade lati beere ohunkohun ti wọn ba fẹ fun itusilẹ awọn eeyan wọn to wa lahamọ ijọba.

Fidio ti wọn fi n kede eyi kun ori ayelujara, bi o tilẹ jẹ pe ọpọ igba ni ijọba apapọ Naijiria maa n sẹ jalẹ pe ko si idunadura laarin awọn ati awọn agbebọn yii