Johnson & Johnson baby powder: Iléeṣẹ́ apoògùn wọ́gilé ìpara ọmọdé ‘baby powder’ lẹ́yìn tí àwọn èèyàn ní ó ń fa àrùn jẹjẹrẹ

Johnson & Johnson baby powder

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ileeṣẹ apoogun, Johnson & Johnson yoo dẹkun ati maa pese ipara ọmọde rẹ, “Johnson’s baby powder” kaakiri agbaye bẹrẹ lati ọdun to n bọ.

Ikede yii lo n waye lẹyin ọdun meji ti ileeṣẹ naa ti fopin si ipara ọmọde naa nilẹ Amẹrika.

Ṣaaju ni ọpọ awọn obinrin kan ti kọkọ n gbe ileeṣẹ naa lọ sile ẹjọ lẹyin ti wọn ni awọn ipara ọhun ni awọn eroja ‘asbestos’ to n fun awọn obinrin ni arun jẹjẹrẹ, ovarian cancer.

Amọ ileeṣẹ ọhun ni lẹyin ọpọ iwadii to ti le lọpọ ọdun, awọn gbagbọ pe ko si ewu kankan ninu lilo ipara ọmọde ti awọn n ṣe.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ J&J fi lede, wọn ni “Gẹgẹ bii ọkan lara awọn igbesẹ tuntun nileeṣẹ wa, a ti pinnu lati wọgile awọn ipara ọmọde oni pauda wa lawọn orilẹ-ede kan kaakiri agbaye.”

Bo tilẹ jẹ pe wọn fẹ wọgile ipara ọmọde ọhun, ileeṣẹ naa ṣi tẹpẹlẹ mọ ọrọ wọn pe ko sewu ninu ipara ọmọde naa.

Wọn ni “A duro digbi lẹyin awọn iwadii ijinlẹ wa ti awọn eleto ilera ṣe kaakiri agbaye pe ipara ẹlẹfun awọn ọmọde wa ko ni ewu kankan ninu, bẹẹ si ni ko ni eroja to maa n fa arun jẹjẹrẹ.”

Inu ọdun 2020 ni ileeṣẹ J&J kede pe oun yoo dẹkun ati maa ta ipara ẹlẹfun naa nilẹ Amẹrika ati Canada.

Lọdun naa lọhun, wọn ni awọn yoo ṣi maa ta ipara naa lawọn orilẹ-de mii kaakiri agbaye.

Ninu iwadii kan ti ileeṣẹ iroyin Reuters sẹ lọdun 2018, wọn ni ileeṣẹ J&J mọ pe ipara naa ni eroja to le fa arun jẹjẹrẹ, amọ wọn kọ lati sọrọ.

O ti le ni aadoje, 130, ọdun ti ileeṣẹ naa ti n ta ipara ọmọ naa.