Ìkọlù kankan kò lè wáyé ní Eko, a wà nílé fún wọn – Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Google
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti kede pe mimi kan ko lee mi ẹnikẹni nipinlẹ Eko nitori ni ako ni awọn wa.
Eyi ko ṣẹyin bi ileeṣẹ ọlọpaa naa ṣe ni lootọ ni awọn gbọ nipa ọrọ ahesọ pe o ṣeeṣe ki ikọlu awọn agbesunmọmi waye nipinlẹ Eko.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin fi lede, lo ti sọ pe awọn gbọ ahesọ pe o ṣeeṣe ki ipinlẹ Eko wa lara awọn ibi ti awọn agbebọn fẹ ṣe ikọlu si.
‘’Eyi lo mu ki kọmisọnna ọlọpaa, Abiosun Alabi fi to awọn agbofinro ikọ ọtẹlẹmuyẹ, State Intelligence Bureau leti to fi mọ awọn ọga ni awọn agọ ọlọpaa kọọkan lati duro wamuwamu.’’
‘’Eyi ni lati jẹki eto aabo wa ni pẹsẹ ki ikọlu kankan ma ṣe waye’’
Ti ọsan ti oru ni ikọ Agbofinro n ṣiṣẹ nipinlẹ Eko
Bakan naa ni wọn n ṣiṣẹ pẹlu awọn ikọ agbofinro miran lati ri pe awọn agbebọn ko da alaafia ipinlẹ Eko ru.’’
Ọga ọlọpaa naa lo asiko yii lati fi ọkan awọn olugbe ilu Eko ni ọkan balẹ wi pe ko ni si ewu nitori gbogbo ikọ agbofinro lọ duro wamuwamu si ẹnu iṣẹ wọn.
O fikun un pe ki onikaluku maa lo si ibi iṣẹ rẹ lai si ifoya tabi aibale ọkan pe ewu le wa fun wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa naa rọ awọn eniyan lati tete ta ọlọpaa lolobo ti wọn ba ri ohunkohun to jọ mọ ohun ti wọn ko ri ri ni ayika wọn.
Bakan naa ni wọn parọwa si awọn eniyan lati maa ṣe akiyesi, ki wọn si maa sọ ara ṣe.














