Ọwọ́ àwọn agbófinró Abuja tẹ afurasí 480 tó sá kúró lọ́gbà ẹ̀wọ́n Kuje

Ọgba ẹwọn Kuje

Oríṣun àwòrán, other

Awọn alaṣẹ olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja ni ọwọ ti tẹ eeyan ọrinlerinwo kan ti wọn funra si pe wọn wa lara awọn ẹlẹwọn to sa kuro lọgba ẹwọn Kuje lasiko tawọn agbebọn fi kọlu ọgba ẹwọn naa laipẹ yii.

Wọn ni awọn ile akọpati lagbegbe Maitama ati Wuse II ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi naa.

Adari ikọ agbofinro to n wa awọn ẹlẹwọn naa, Bennett Igweh sọ pe awọn ẹlẹwọn to sa lọ naa, pupọ ninu eyi to jẹ ọkunrin, ti lọ pamọ sinu awọn bareke, ile ofifo atawọn ibuba miran lati maa hu iwa ibi wọn.

Bakan naa ni Ọgbẹni Igweh tun ṣalaye pe awọn agbofinro mu awọn afurasi naa pẹlu aṣọ ọlọpaa, ẹrọ ibanisọrọ ilewọ, ibọn atawọn ohun ija oloro miran.

Agbofinro naa ṣalaye pe awọn yoo tubọ maa ṣe itankalẹ iwadii wọn kaakiri ileto kereje mọkanlelogun to wa kaakiri ilu Abuja ninu eyi ti Kabusa, Gishiri, Waru ati Wasa wa.

Igweh sọ pe awọn ẹṣọ alaabo ko ni faye gba awọn ọdaran kankan mọ lati maa domi alaafia ilu Abuja ru.

Bakan naa lo ṣalaye pe wọn yo ṣe ayẹwo gbogbo wọn daradara lati mọ bi wọn ṣe jẹ.