Ǹkan ti ọlọ́pàá sọ rèé lórí ìjà Fulani àti OPC tó mú ẹ̀mí èèyàn mẹ́rin lọ ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Screenshot
O to eeyan mẹrin to padanu ẹmi wọn, ọpọ si farapa yanayana,lẹyin ti ikọlu kan waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ Oodua,OPC, ati awọn Fulani kan ni agbegbe Ajasse Ipo to wa ni ijọba ibilẹ Irepodun ni ipinlẹ Kwara lọjọ Ẹti.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Kwara, Ajayi Okasanmi, fi idi iṣẹlẹ naa mule, ti o si ni ija naa bẹrẹ ni dede agọ mẹfa abọ ni irọlẹ ọjọ Ẹti.
O ni iwadi ti bẹrẹ lori nkan to fa ija naa ati pe awọn ko ti le sọ nkan pato to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ Oodua ati awọn Fulani.
“Ẹmi awọn eeyan mẹrin lo ba iṣẹlẹ naa lo ti ọpọlọpọ awọn miiran si ṣeṣe ''
“Nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa gbọ si iṣẹlẹ naa, kọmisana ọlọpaa ni ki awọn ọlọpaa lọ sibẹ
“Lọwọlọwọ bayi, alaafia ti jọba pada ni agbegbe naa taa si ti ko awọn to padanu ẹmi wọn lọ si ile igbokupamọ si ti awọn miiran to farapa si wa ni ile iwosan, nibi ti wọn ti n gba itọju bayi.








