Irọ́ lọ̀gá ṣọ́jà 81 division pa pé ọlọ́pàá yìnbọn sí ṣọ́jà tó pa Ìsìpẹ́tọ̀ Orukpe, ẹ ní kó gbé ṣọ́jà náà jáde - iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Èkó

Oríṣun àwòrán, lagos state police command
Irọ nlanla lọga ṣọja ọwọ kọkanlelọgọrin ileeṣẹ ọmọogun Naijiria to fikalẹ si Ọjọọ nilu Eko, Ọgagun Umar Musa pa pe ọlọpaa kan yinbọn si ṣọja lasiko wahala to waye laarin ọlọpaa atawọn ṣọja kogbokun (Private) kan lọjọ kẹta oṣu kẹjọ, eleyi to sọ ọlọpaa kan di ero ọrun.
Ninu atẹjade kan eyi ti ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko fi sita, o ni oun gbọ “ọrọ kan ti wọn gbe sita pe “ọga ṣọja ọwọ kọkanlelọgọrin ileeṣẹ ọmọogun Naijiria to fikalẹ si Ọjọọ nilu Eko, Ọgagun Umar Musato n fipo silẹ bayii sọ pe ‘ọlọpaa yinbọn fun ṣọja eleyi to ba eti rẹ’. Bi o tilẹ jẹ pe a n ṣọfọ, sibẹ a o dide tako iroyin irọ.”

Oríṣun àwòrán, lagos state police command
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ṣọja purutu ti wọn to ọgbọn niye ni wọn kọlu awọn ọlọpaa marun un ti wọn n da ọkọ duro lojuna wọn ki ọkọ akẹru nla kan lee gbori wọ opopona marosẹ naa.
O ni o jẹ ohun to bani ninu jẹ pupọ pe awọn ṣọja kopgbokun yii lee lu ọga ọlọpaa to ṣaaju ikọ ọlọpaa naa, ti wọn si gba apo ọta ibọn rẹ, wọn gbe ripẹtọ meji lọ pẹlu ibọn wọn, ripẹtọ kẹta ti wọn fẹ gbe lo yinbọn soke lati le wọn sẹyin ti wọn fi sa. Ko si si ẹnikẹni to fara gbọta ibọn.

Oríṣun àwòrán, lagos state police command
“Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko wa n ke si ileeṣẹ ọmọogun lati gbe ṣọja ti ibọn ba jade.”
O ni awọn alaṣẹ ọlọpaa ṣi n reti abajade esi iwadii ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria n ṣe lori rẹ. Ki wọn si fi oju awọn ṣọja to pa ọlọpaa naa, Ripẹtọ Monday Orukpe sita ki wọn si da ibọn AK 47 meji ati apo ọta ibọ mẹta ti awọn ṣọja naa ko lọ pada
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ?
Ni ọjọ kẹta oṣu kẹjọ ọdun 2022, awọn sọja kan n kọja lọ ninu ọkọ bọọsi nla kan to gbe wọn loju ọna marosẹ Eko si Badagry, nibi ti wọn si ha sinu sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ.
Diẹ lara awọn sọja naa sọkalẹ, ti wọn si fi ẹsẹ rin de ikorita kan nibi ti awọn ọlọpaa ti n dari lilọ bibọ ọkọ.
Ikorita ọhun ni iroyin sọ pe wọn ti lu awọn ọlọpaa naa ni alubami, wọn ko ibọn wọn, wọn si tun gbe awọn mejeeji lọ.
Lara awọn meji ti wọn ko lọ ni isipẹtọ Monday Orukpe wa.
Wọn fi iya jẹ awọn ọlọpaa mejeeji yii ki wọn to ri wọn gbe lọ si ile iwosan nibi ti Insipẹtọ Orukpe ku si.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin sọ fun BBC nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ pe awọn ti n jiroro pẹlu ileeṣẹ ologun lati yanju ọrọ naa.












