Àsìkò tí tó fún àwọn ọ̀dọ́ láti gbá ìṣàkóso orílẹ̀èdè Nàìjíríà- Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Peter Obi
Olujide sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ti rọ awọn ọdọ orilẹede Naijiria lati gba isakoso orilẹede Naijiria pada lọwọ ti n ṣe ijọba lọwọlọwọ.
Obi sisọ loju ọrọ naa nigba ti o darapọ mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour Party lati si ofisi tuntun ti ọdọ kan, ti o jẹ alatilẹyin rẹ gbe kalẹ fun ẹgbẹ oṣelu niluu Owerri ni ipinlẹ Imo.
O ni niṣe ni inu ma dun ti oun ba ri pe awọn ọdọ ba gbinyanju lati gba isakoso orilẹede Naijiria nitori pe ko ye ki orilẹede yii tẹsiwaju bayi.
Obi tẹsiwaju pe ti oun ba fi le di Aarẹ orilẹede Naijiria, oun setan lati mu orilẹede yii kuro nipo ẹru to wa, ti oun si gbẹ fun awọn ọdọ ati awọn eeyan ilu to jiya lori bi Naijiria yoo ṣe ni itẹsiwaju.
“Inu mi dun bi mo ṣe wa si ofisi tuntun ti ọkan lara awọn alatilẹyin wa kọ fun wa .”
“A gbọdọ gba Naijiria pada, ki a gbe fun awọn ọdọ nibi to yẹ kowa.
“Ti asikọ ba to, a yi orilẹede Naijiria pada si dada ti n ba di Aarẹ orilẹede Naijiria, nitori pe ko yẹ ki orilẹede naijiria tẹsiwaju bayi.”











