Ẹgbẹ́ NLC kọ lẹ́tà sí Buhari pé kó fi ìdá àádọ́ta kún owó oṣù òṣìṣẹ́ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria, NLC ti kọwe ranṣẹ si Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko fi kun owo oṣu awọn osisẹ orilẹede Naijiria pẹlu ida adọta ninu ọgọrun nitori bi gbogbo nnkan ṣe gbowo lori lasikoyi.
Ninu atẹjade kan to fi ransẹ si Aarẹ Buhari, ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria bu ẹnu atẹlu bi awọn gomina ṣe ni ijọba yọ owo orí epo bẹntiróòlù, pe ki ijọba di ọjọ ti awọn osisẹ yoo ma lo nibi iṣẹ ku si adọta ọdun ati adinku si isẹ akanṣe ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin yoo ma ṣe.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Ayuba Wabba sapejuwe awọn gomina gẹgẹ bi ọta ijọba Aarẹ Muhammadu Buhuri fun imọran ti wọn gbe kale.
O ni ki Aarẹ ma ṣe gba imọran adinku si ọjọ ti osisẹ ma lo lenu isẹ ijọba, sugbọn ki Aarẹ gbinyanju lati fi owo kun owo oṣu awọn osisẹ.
Wabba ni nkan ti jẹ awọn osisẹ logun bayi, ti o si le ṣe won ni ọpọlọpọ anfani ni ki Aarẹ fi owo kun owo oṣu awọn osisẹ.
“Pẹlu bi nkan ṣe wa lọwọlọwọ bayi, nkan ti awọn osisẹ fẹ ni ki ijọba fi owo kun owo oṣu wa pẹlyu ida adọta ninu ọgọrun.”











