Kò sí ẹlẹ́gbẹ́ Atiku láàrín Tinubu àti Obi - Dino Melaye

aworan Dino Maleye

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Agbẹnusọ fun ipologo Atiku Abubakar, Dino Melaye ti sọrọsoke lori iru eeyan ti oludije PDP je.

O sapejuwe igbakẹji Aarẹ tẹlẹ ri ati oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, Akitu Abubakar gẹgẹ bi ẹni ti o ta yoo.

Dino ni pe o yato larin awọn olujide sipo aarẹ yoku to n jide lọdun 2023.

Malaye sọrọ naa nigba ti o darapọ mọ ile isẹ tifisan kan ni ipari ọsẹ.

O ni awọn oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ati oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ko yẹ ni ẹni ti yoo ma lọkitipọ mọ Atiku Abubakar lọwọ.

O tẹsiwaju pe ẹgbẹ oṣelu ti yoo nira fun lati bori idibo kankan Naijiria, ni ẹgbẹ oṣelu APC.

“Ẹgbe oṣelu APC ko ṣe afihan olujide kankan nitori pe wọn ti iba orilẹede Naijiria jẹ jina.”

Maleye ni ọrọ ti Mínísítà abẹle fún ọrọ osiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Festus Keyamo sọ si Atiku Abubakar lo jẹ ọrọ buruku.

O ni ko ṣeeṣe ki eeyan gbe olujide sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu fun awọn ọmọ orilẹede lai wo bi omugọ.

Dino ni: “APC sapejuwe Atiku gẹgẹ bi olujide ti ko le bori ninu idibo aarẹ tọdun 2023 sugbọn awọn gan an pẹlu bi wọn ti iṣejọba orilẹede yii, olujide kankan lati ninu ẹgbẹ naa ko le bori ninu eto idibo lorilẹede Naijiria.

Aṣofin tẹlẹ lati ipinlẹ Koji ni ẹgbẹ oṣelu APC padanu iwuwasi lati ṣe ijọba orilẹede Naijiria, nitori ọpọ eeyan ni ko fẹran wọn mọ ninu eto ijọba.