Ìdí réè tí àwọn ọmọ mi kò fi gbọdọ̀ pè mi ní Sanyeri-Olaniyi Afonja

Aworan Sanyeri ati awọn ẹbi rẹ.

Oríṣun àwòrán, Olaniyi Afonja Sanyeri

Ninu awọn oṣere tiata Yoruba adẹrinposonu, odu ni Olaniyi Afonja jẹ.

Sanyeri gẹgẹ bi ọpọ ṣe mọ si jẹ ilumọọka elere sinima Yoruba ti o ni ọpọ awn ololufẹ lori ayelujara.

O ba ileeṣẹ iwe iroyinNaijiria Punch sọrọ laipẹ yi to si ni ohun to ṣe oataki si oun kii ṣe ọkọ ayọkẹlẹ tabi ohun meremere aye mii bi kii ṣe awọn ọmọ oun.

Ọdun 2007 ni Sanyeri ṣe igbeyawo to si ni ẹni ọdun mọkanlelọgbọn loun nigba ti oun di ẹni to ni iyawo lọọdẹ.

O ṣalaye pe awọn ọmọ oun ko si ni Naijiria ṣugbọn eyi ko ni koun ma kọwọn lẹkọ nipa asa ati iṣesi Yoruba.

Idọbalẹ lawọn ọmọ mi ma fi n ki mi

Sanyeri mẹnu ba pataki ti oun so mọ kikọ ọmọ lẹkọ ati titọ ọmọ lọna ti ko fi ni naka alebu si oun lọjọ iwaju gẹgẹ bi obi.

Awọn mii fẹran ki wọn maa paarọ aṣọ, ile kikọ lawọn mii yan laayo.Lọdọ awọn ẹlomiran ọkọ ni o mumu lọkan wọn.Amọ ni temi ko si idokowo ti mo mu ni pataki ju pe ki n fi owo sidi ọmọ titọ. Ko si nkan naa ti mo le tori rẹ fi ọjọ iwaju awọn ọmọ mi ta tẹtẹ''

''Bi mo ni bi mi o ni, gbogbo apa ni mo maa ṣa lati ri pe awọn ọmọ miko ni naka alebu simi lọjọ iwaju gẹgẹ bi baba ti ko ṣe ojuṣe rẹ''

Nipa kikọ ọmọ lẹkọ yi, o ni oun tẹ aṣa Yoruba mọ wọn leti debi pe igba ti wọn ba fẹ ki oun gẹgẹ bi baba, wọn maa n dọbalẹ ni.

''Bi a baa n sọrọ lori ipe ni wn le ki mi pẹlu ẹnu ṣugbọn bi a ba foju kan ara wa, idọbalẹ ni wọn gbọdọ fi ki mi.''

Ko jọ! Awọn ọmọ mi kii pe mi ni Sanyeri

Lori orukọ to n jẹ ninu awọn ere sinima taa mọ si Sanyeri, akọroyin beere lọwọ Niyi Afonja pe ṣe awọn ọmọ rẹ a maa pe lorukọ yi.

Esi to fọ pada si ni pe ko si ohun to jọ bẹ.

O ni lọdọ awọn ọmọ oun, Daddy ni wn maa n pe oun ati pe inu sinima lorukọ yi ti n jẹ yọ kii ṣe orukọ toun n jẹ gangan.

O wa gba awọn obi lamọran pe ki wọn mu ẹkọ ọmọ ni pataki paapa eleyi to ni ṣe pẹlu aṣa ati iṣe Yoruba ki wọn ma ba gbagbe orisun wọn.