Àlàyé rèé lórí ohun tó fa ìpàdé tó ń wáyé lọ́wọ́ láàrín Obasanjo, Tinubu, àtawọn ọbalayé ilẹ̀ Yorùbá l'Abeokuta

Nilu Abẹokuta, lọwọlọwọ bayii ipade n lọ lọwọ laarin oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Ahmed Bọla Tinubu pẹlu Aarẹ Naijiria nigbakan ri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ.
Gẹgẹ bi iroyin to n tẹ BBC News Yoruba lọwọ, awọn lọbalọba kan nilẹ Yoruba ni wọn pe ipade naa.
O si wa laarin Tinubu ati agba oṣelu Oluṣẹgun Ọbasanjọ àti àwọn eekan ọmọ Yoruba miran ki awọn ọmọ Yoruba lee tọ si oju kan naa lasiko idibo apapọ to n bọ lọdun 2023.

Lara awọn eekan to wa nibi ipade naa eyi to n lọ lọwọ bayii ni gbọngan ikawe nla ti Oluṣẹgun Ọbasanjọ Library ni Aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu.
Awọn mii ni olori ile aṣojuṣofin lorilẹede Naijiria, Họnọrebu Gbajabiamila, awọn gomina ipinlẹ Ogun nigba kan ri, Oluṣẹgun Ọṣọba ati Gbenga Daniel.
Pẹlu gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun atawọn eekan miran lẹgbẹ oṣelu naa.
Bakan naa lawọn Ọbalaye kannrin-kannrin nilẹ Yoruba pẹlu wa nibi ipade naa.








