Babagana olùdámọ̀ràn lórí ètò aàbò Nàìjírà, kọ̀wé fipò sílẹ̀ tàbí kí Buhari da ẹ dúró- Arewa Youth Assembly

Lónìí ní ètò ìwọ́de tún bẹ̀rẹ̀ pé kí olùdámọ̀ràn ìjọba àpapọ̀ nípa ètò ààbò, Babagana Monguno kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ látàrí ètò ààbò tó mẹ́hẹ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Egbẹ awon ọdọ lati ariwa Naijiria ti wọn n je Arewa Youth Assembly (AYA) lo seto iwode naa ni National Assembly nilu Abuja to jẹ olu ilu Naijiria.
Ninu iwode naa ni won ti so pe ki oludamoran fun ijoba Buhari lori ọrọ eto aabo, Babagana Mungoro ko kọwe fipo silẹ tabi ki Aare Muhammade da a duro lenu iṣẹ.
Wọn ni pe ipo ti eto aabo wa bayii ni Naijiri ako fihan pe enikeni n sise bi o ti ye nibe lati ọdun meje ti wọn ti yan Mungoro sipo ẹlẹgẹ yii.
- Gómìnà Oyetola fẹ́ fi ìbò ìjọba ìbílẹ̀ rán ìpínlẹ̀ Osun sínú ọ̀gbun gbèsè tuntun ni - PDP Osun
- Tani ọkùnrin ọlọ́dẹ orí tí ayé ń pariwo kiri pé ó gba ìwòsàn ní Akure ni àná?
- Gómìnà gbé òfin kalẹ̀, ẹ yìnbọn pa ọlọ́kadà tó bá tápà sí kónílé-ó-gbélé alẹ́
- Wo bí arábìnrin yìí ṣé dáhùn sí ìbéèrè níbi ètò ìsìnkú ará rẹ̀
- Ìhá Buhari àtìjọba rẹ̀ sọ́rọ̀ ìjínigbé ń gbin ẹ̀rù sọ́kàn gbogbo ọmọ Nàìjíríà - Afenifere
- Akọ̀ròyìn Zambia, Dingindaba Jonah Buyoya gbà àmì ẹ̀yẹ BBC Komla Dumor-
Egbe yii ni pe iye awon eeyan ti won n jigbe ati awọn ti wọn n pa nipakupa ti pọju ni eyi to ba ni lọkan jẹ.
Bakan naa ni wón ke si Aare Buhari lati ranti awọn ileri to ṣe ko to wọle sipo Aare Naijiria.
Wọn ni ko lo agbara rẹ gẹ\gẹ bii ologun tẹlẹri ati aarẹ bayii ko wa nkan se si ọrọ eto aabo yii nitori ko si owo lati san owo itanran ajinigbe mọ.

Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Arewa Youth Assembly (AYA) ti ṣe ìwọ́de lẹnu ọ̀nà ilé ìgbìmọ̀ asòfin to wa niluu Abuja lati pè fún yíyọ olùdámọ̀ràn ìjọba àpapọ̀ lórí ètò ààbò, Babagana Monguno látàrí ètò ààbò tó mẹ́hẹ lorilẹ ede Naijiria.
Saájú ètò ìwọ́de tó waye lonii, ni ẹgbẹ Arewa Youth Assembly (AYA) ti fún aarẹ Muhammadu Buhari ní gbèdéke ọ̀sẹ̀ méjì lati yọ Monguno kuro nípò.
Nigba ti agbẹnusọ fún ẹgbẹ Arewa Youth Assembly (AYA) Ali Mohammed, ń sọrọ, o ni Babagana olùdámọ̀ràn lórí ètò aàbò Nàìjírà, kọ̀wé fipò sílẹ̀ tàbí kí Buhari da ẹ dúró- Arewa
" Eto aabo orilẹ ede Naijiria ti di kólórí di orí ara rẹ̀ mú, ìwà ìpànìyàn, ìjínigbé, olè abbl tún n pọ̀ si ju, bó se wà tẹlẹ lọ lorilẹ ede Naijiria, lasiko ti , Babagana Monguno ti di olùdámọ̀ràn ìjọba àpapọ̀ lórí ètò ààbò.Ní èyí, tó fi yé wa pé Babagana Monguno kò mọ nnkankan nipa eto aabo orilẹ ede Naijiria."
- A ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì, àyafi tí ìjọba Nàìjíríà bá.....àwọn òṣìṣẹ́ iná mọ̀nàmọ́ná
- Tani ọkùnrin ọlọ́dẹ orí tí ayé ń pariwo kiri pé ó gba ìwòsàn ní Akure ni àná?
- Wo bí arábìnrin yìí ṣé dáhùn sí ìbéèrè níbi ètò ìsìnkú ará rẹ̀
- Gómìnà gbé òfin kalẹ̀, ẹ yìnbọn pa ọlọ́kadà tó bá tápà sí kónílé-ó-gbélé alẹ́
- Gómìnà Oyetola fẹ́ fi ìbò ìjọba ìbílẹ̀ rán ìpínlẹ̀ Osun sínú ọ̀gbun gbèsè tuntun ni - PDP Osun
OMohammed tẹ̀síwájú pé "Bi wọn se n fi ojoojumọ pa ọmọ orilẹ ede Naijiria , se ni olùdámọ̀ràn ìjọba àpapọ̀ lórí ètò ààbò, Babagana Monguno ń jẹ̀gbádùn , to si ń fọlá-mutí ni ọfiisi rẹ̀, nigba to mọ pe ọwọ́ awọn ọ̀daràn naa kò leè mú òun.
"A o lee gba ki eto aabo orilẹ ede Niajiria túbọ̀ máa kùnà tabi forí sánpọ́n mọ̀ ọ́n, nitori naa kí Babagana Monguno máa lọ, kó kúrò nípò rẹ̀. Kò ní nnkankan tó mọ̀ nípa ètò ààbò, awọn èròńgbà rẹ̀ kò bá ìgbà mu mọ́.
"Bi wọn se n fi ojoojumọ pa àwa tí a wà ni apá Ariwa , ti su wa, idi niyi ti a se sọ pe ki wọn yọ Babagana Monguno. .Ìyà ń jẹ wà ju awọn ẹkun miran lọ lorilẹ ede Naijiria. Eto aabo tó mẹ́hẹ n ṣe akoba fun ounjẹ ati awọn ohun amayedẹrun ni ọdọ wa , ni eyi ti o jẹ ki òsì ati ìsẹ́ tún pọ si"
Àwọn ẹgbẹ́ Arewa ti wọ́n ń darí ètò ìwọ́de náà sọ pé kí ìwà ìpaniyan,ìjigbé àti àwọn ìwà ìbàjẹ́ míràn tó ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, lásìkò tí Babagana Monguno jẹ́ olùdámọ̀ràn ìjọba àpapọ̀ nípa ètò ààbò ń tún po si
Ahmed Nasir, láti ìpínlẹ̀ Kaduna,tó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà tún sọ̀rọ̀ nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin pé kí wọ́n yọ olùdámọ̀ràn ìjọba àpapọ̀ nípa ètò ààbò nípò.

- Wo àwọn ọkùnrin tó ń múra bí obìnrin àti ohun tí àwùjọ ń fi ojú wọn rí
- Ń kó gbá àádọ́ta bílíọ́nù lóṣooṣù lọ́wọ́ Ambode – Tinubu
- Ó ṣeéṣe kí Salman Rushdie pàdánù ojú kàn nítorí ọ̀bẹ tí wọ́n gún un lọ́rùn - Agbẹnusọ
- Àwa adarí tiraka láti mú ìbáṣepọ̀ àláfíà bá Nàíjíríà àmọ́ ìyapa ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣèdíwọ́ - IBB
- ‘Muslim Muslim Ticket’ tí APC ṣekò ní ìtẹ́wọ́gbà - Kukah
- Ẹ̀yin agbébọn, ẹ kúrò nílẹ̀ Yorùbá tàbí kẹ́ ẹ tún rí ìjà mí - Sunday Igboho














