Njẹ́ èèyàn lè bá àwọn mọ̀lẹ́bí àti ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀ níbi ìsìnkú ará rẹ̀ bíi?

Oríṣun àwòrán, Marina Smith Foundation
Ojojumọ ni imọ sayẹnsi n gberu si.Yala nipa ilera tabi ipese ounjẹ orisi ọna lawọn onimọ fi n mu iyatọ ba igbe aye ẹdamọniyan.
Ninu iroyin eleyi taa mu tọ yin wa, arabinrin kan to ti di oloogbe lanfaani lati dahun ibeerere lọwọ awọn to wa sibi isinku rẹ.
Bawo lo ṣe gbe gba?
Marina Smith lorukọ ẹni taa n wi yi to si jade laye lẹni ọdun mẹtadinlaadọrun loṣu kẹfa ọdun yi.
- Àwọn òṣìṣẹ́ àjọ amúnáwá yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lọla
- Nkan tí ọlọ́pàá sọ rèé nípa arákùnrin ''afurasí agbésùmọ̀mí '' tó múra bí obìnrin tí ọwọ́ bá lEko
- Ọkùnrin kàn pàdánù ẹ̀mi rẹ ní ilé itùrà lẹ́yìn tí ó pàdé olólùfẹ́ orí ayélujára-
- Egungun Oloolu ti ilẹ̀ Ibadan fojú han aráyé! Gbọ́ àwọn ǹkan tó ń dẹ́rù ba obìnrin, ọmọde nípa rẹ̀ àti èèwọ̀ rẹ̀
Ọmọ rẹ ọkunrin ni ileeṣẹ rẹ sagbekalẹ ẹrọ oni fidio kan to mu ki awọn to wa sibi isinku rẹ lanfaani beere ọrọ lọwọ iya rẹ to ti ku.
Gẹgẹ bi ọmọ rẹ ṣe sọ, o ni imọ tẹkinọlọji yi jẹ ki ''mama mi jọ pe wọn wa pẹlu wa nibi isinku rẹ''
Arakunrin Smith to jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ ileeṣẹ StoryFile sọ fun BBC pe imọ ẹrọ yi tunmọ si pe''bi eeyan ba ku yoo ṣeeṣe ki awọn mọlẹbi ba sọrọ bi igba to ṣi wa laye''
Ileeṣẹ naa sọ pe ọpọ ọna ni awọn eeyan yoo le gba lati lo imọ ibaraẹnsisọrọ tuntun yi.
Wọn ni eleyi ti Smith ṣe fun mama rẹ yi''gbe awọn ohun pataki nipa igbe aye iya rẹ sita fawọn to nifẹ rẹ to si ni itumọ gidi gaan si wọn''
Smith ni awọn ọrọ ti mama oun sọ jẹ ọrọ araarẹ, kii ṣe ọrọ ti ẹrọ AI taa mọ si artificial intelligence gbe sita.

Oríṣun àwòrán, StoryFile
Bo ṣe gba ṣiṣẹ
Lati le ṣe iru fidio ibaranisọr yi, ẹni naa gbọdọ ti ṣe fidio nibi ti yoo ti dahun awọn ibeere nipa igbesi aye rẹ.
Lyin to ba jade laye tan, ẹrọ AI kan yoo maa ṣa fọnran to ṣe rẹgi si ibeere tawọn to ba wa si bi isinku naa n beere.
Ẹni to wa ninu fiidio naa yoo dabi pe o n tti si ibeere kọọkan ti wn baa n beere nibẹ.
- Gómìnà Oyetola fẹ́ fi ìbò ìjọba ìbílẹ̀ rán ìpínlẹ̀ Osun sínú ọ̀gbun gbèsè tuntun ni - PDP Osun
- Ìhá Buhari àtìjọba rẹ̀ sọ́rọ̀ ìjínigbé ń gbin ẹ̀rù sọ́kàn gbogbo ọmọ Nàìjíríà - Afenifere
- Nkan tí ọlọ́pàá sọ rèé nípa arákùnrin ''afurasí agbésùmọ̀mí '' tó múra bí obìnrin tí ọwọ́ bá lEko
- Ọ̀wọ́ngógó ọjà ní Nàìjíríà gbéra dé ìdá 19.6%, wo ohun tó túmọ sí fáráàlú
- Mọ̀ síi nípa William Ruto, ààrẹ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní Kenya
- Mọ̀ síi nípa àwọn aláwàdá Yorùbá tó ti dolóògbé ṣùgbọ́n tí ayé ṣì n pariwo wọn
Rollo Carpenter to da ẹrọ chatbot ti orukọ rẹ n jẹ CleverBot silẹ ti ko si ni ajọṣepọ kankan pẹlu ileeṣ StoryFile sọ pe ẹrọ yi n gbiyanju lati mu idahun tirẹ wa ni, ko lo AI lati fesi pada.
''Yoo kan mu esi kan ninu eleyi ti wọn ti gba kalẹ, yoo si lo ọgbọn lati jẹ ki awọn eeyan gbe soju iran''














