William Ruto: Mọ̀ síi nípa William Ruto, ààrẹ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní Kenya

William Ruto

Oríṣun àwòrán, Williams ruto

Wọn ti kede William Ruto gẹgẹ bii aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹede Kenya.

ni kete ti wọn si kede esi idibo naa to si ti tẹw gba iwe ẹri rẹ lo ba awọn ọmọ orilẹede naa sọrọ to si kan sara si wọn pe ko si idi fun ijọba oun lati maa fi nnkan bo araalu loju.

bakan naa lo fi da awọn alatako rẹ loju pe ijọba oun ko nigbẹsan tabi na ika aleebu si ẹnikẹni nitori asiko ifọwọsowp lorilẹede naa wa bayii.

Mo ṣetán láti sa ipa mi fún ìdàgbásòké Kenya- Ruto William igbákejì aarẹ̀ Kenya tẹ́lẹ̀ ṣèlérí lẹ́yìn ìkéde

Nigba to n ba awọn ọmọ orilẹede Kenya sọrọ lẹyin ti wọn kede pe oun ni araalu dibo yan, William Ruto ni ijọba ti ko ni fi igba kan bọkan ninu fun araalu loun yoo gbe kalẹ. Bẹẹni o ni iṣejọba oun yoo ko akoyawọ.

"Mo fẹ ṣeleri fun awọn eeyan orilẹede Kẹnya, lain naani ẹnikẹni yoowu ninu awọn oludije ti wọn lee dibo fun, pe ijọba wọn ni ijọba yii yoo jẹ.

"Mo fẹ sọ fun awọn alatako mi pe ko si idi fun wọn lati bẹru o nitori pe ko si aye fun ẹsan. Mo mọ pe ipele ti gbogbo wa gbọdọ ṣe ohun to tọ lorilẹede wa wa bayii.

"Ko si akoko fun wa labi ru ẹru erin maa fẹsẹ wa iho irẹ. Ko si aye lati maa na ika aleebiu. Gbogbo wa gbọdọ pawọpọ ṣe iṣe fun ilọsiwaju orilẹede Kenya."

Bi esi idibo naa ṣe lọ niyi

awọn ololufẹ Ruto n dawọ idunnu

Eyi ni awofin esi idibo aarẹ lorilẹede Kenya, eyi to gbe Willian Ruto de ipo.

William Ruto ni wọn kede gẹgẹbi aarẹ ti ilu dibo yan pẹlu ida aadọta o le diẹ ibo naa, 50.49%

Taila Odinga lo tẹle e pẹlu ida mọkadinlaadọta o din diẹ apapọ ibo ti wọn di (48.85%).

Lẹyin rẹ ni George Wajackoyah ati David Mwaure. Ibo ti wọn ni ko to ida kan ninu ọgọrun (1%)

Wọn kede William Ruto gẹg bi aarẹ tuntun lorilẹede Kenya

William Ruto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn kede William Ruto gẹgẹ bi aarẹ tuntun ti ilu dibo yan lorilẹede Kenya lọjọ Aje.

Ajọ eleto idibo orilẹede Kenya IEBC kede William Ruto gẹgẹbi olubori ibo aarẹ lorilẹede naa lẹyin ọjọ marun un ti wọn fi ṣe ayẹwo esi ibo naa to waye lọjọ kẹsan an oṣu kẹjọ.

William Ruto lewaju Raila Odinga pẹlu ibo miliọnu meje o le ẹgbẹrun mẹrindinlọgọsan ati mọkan lelogoje, 7, 176, 141

Ida aadọta o le diẹ ibo ti awn oludibo di lj kẹsan an oṣu kẹjọ ọdun 2022 ni William Ruto ni to fi gbẹyẹ mọ Raila Odinga lọwọ.

Ta ni William Ruto, aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ fi ibo gbe wọle lorilẹede Kenya?

Ruto

Oríṣun àwòrán, AFP

Igba ewe William Ruto ṣe apẹrẹ igbe aye awọn mẹkunu lorilẹede Kenya.

Ẹsẹ lasan lo fi rin lọ sile ẹkọ lasiko to fi n kẹkọọ alakọbẹrẹ nitori pe ko ri bata wọ titi to fi pe ẹni ọdun marundinlogun. Bakan naa lo ta adiyẹ ati ẹpa loju popo lawọn ileto igberiko ni Rift Valley.

Nitori naa kii ṣe iyalẹnu pe o n pe ara rẹ ni balogun awọn mẹkunu ninu awọn ipolongo idibo fun aarẹ to ṣe.

Ọgbẹni Ruto n gbe igba idibo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Kenya Kwanza, Swahili for Kenya first pẹlu ileri lati ṣatunṣe eto ọrọ aje nibẹ.

Odinwọn airiṣẹ laarin awọn ọdọ tọjọ ori wọn wa laarin ọdun mejidinlogun ati mẹrinlelọgbọn ṣi wa ni ida ogoji ninu ọgọrun, bẹẹni ọrọ aje orilẹede naa ko faaye ipese iṣẹ silẹ lati gba ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin ọdọ nibẹ siṣẹ lọdọọdun.

Eyi lo mu ko wa ṣeto apejẹ "Hustler Nation" iyẹn, iran awọn to n tiraka lati la gẹgẹ bi orukọ awọn ọdọ to n lakaka lati mu ọwọ lọ si ẹnu nibẹ.

Ẹni ọdun marundinlọgọta ni Ruto, igba akọkọ si niyi ti yoo maa dije fun ipo aarẹ lorilẹede naa. O si n reti oju rere kan naa to gbe e wọle sileegbimọ aṣofin apapọ orilẹede Kenya lati ṣoju ẹkun ariwa Eldoret lọdun 1997.

Ruto atawọn ero kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ọdun 1992 ni William Ruto darapọ mọ oṣelu, lẹyin to ti fi ọpọ ọdun jẹ ọmọlẹyin aarẹ nigba naa, Daniel araMoi.

O wa lara ẹgbẹ awọn ọdọ lẹgbẹ oṣelu Kanu party ti o ṣejọba orilẹede naa fọlọpọ ọdun nigba naa.

Lẹyin to di ọpọlọpọ ipo minisita mu, o di igbakeji aarẹ lọdun 2013 lasiko to dije gẹgẹ bi igba keji aarẹ Uhuru Kenyatta. Eleyi ya ọpọ lẹnu nitori pe ẹgbẹ alatako si ara wọn lawọn mejeeji wa ṣaaju asiko naa.

Wọn wọle sipo nigba naa, ṣugbọn tirela gba aarin wọn kọja lọdun 2018 nigba ti Aarẹ Kenyatta yi oju pada lati pari aawọ pẹlu Odinga eyi to mu ki ireti Ruto yẹ gẹrẹ nitori pe ireti rẹ tẹlẹ ni pe oun ni aarẹ Kenyatta yoo ṣe atilẹyin fun lati di aarẹ lẹyin rẹ.