Àjọ àgùnbánirọ̀ NYSC sọ̀rọ̀ lórí àgùnbánirọ̀ tílé ẹjọ́ rán lọ sẹ́wọ́n nítorí 'yahoo-yahoo'

Oríṣun àwòrán, efcc
Awọn alaṣẹ ajọ agunbanirọ lorilẹede Naijiria, NYSC ti sọrọ lori idajọ ti ile ẹjọ fun ọkan lara awọn agunbanirọ rẹ, Christopher Adetubẹru lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti ọpọ mọ si ‘yahoo-yahoo’ni Naijiria.
Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita loju opo Twitter rẹ, o ni iwa ti Adetubẹru hu buru jai, o si ta ẹrẹ ba orukọ ati ohun gbogbo ti ajọ NYSC lorilẹede Naijiria duro fun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ajọ Agunbanirọ lorilẹede Naijiria, ninu atẹjade naa ti alukoro rẹ, Eddy Megwa buwọlu ṣalaye pe, gbọingbọin lawọn wa lẹyin idajọ naa nitoripe oun gbagbọ pe yoo jẹ ẹkọ nla fun awọn miran to ba fẹ hu iru iwa bẹẹ.
Amọṣa, ajọ NYSC wa yan an pe iwa Adetubẹru ko tumọ si pe bi gbogbo awọn ọdọ to n ṣe agunbanirọ ṣe ri niyi.
Bawo ni Adetubẹru, agunbanirọ to n sinru ilu lọwọ ṣe wa di ẹlẹwọn?
Adetubẹru Christopher Adetoyese, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ko si gbaga awọn oṣiṣẹ agbofinro ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ atawọn iwa kotọ miran lawujọ, EFCC lori ẹsun lilu awọn eyan ni jibiti lori ayelujara.
Ilu Ogbomọṣọ ni Adetubẹru ti n sinruulu labẹ eto agunbanirọ apapọ Naijiria, ṣugbọn Ogele lagbegbe Ẹyẹnkọrin nilu Ilọrin ni ọwọ awọn oṣiṣẹ EFCC lẹkun Ilọrin ti tẹ ẹ.
Ọmọ Ileṣa ni ipinlẹ Ọṣun ni Agunbanirọ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Lọjọbọ to kọja ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara kan nilu Ilọrin ṣedajọ rẹ ti wọn si ran an lọ si ẹwọn ọdun meji fun lilọwọ ninu iwa ọdaran ‘yahoo-yahoo’.
Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ EFCC fi sita loju opo twitter rẹ, Adetubẹru Christopher yoo tun padanu ile ọkọ pẹlu owo to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrun naira, (N900, 000) fun ijọba apapọ.












