Ìhá Buhari àtìjọba rẹ̀ sọ́rọ̀ ìjínigbé ń gbin ẹ̀rù sọ́kàn gbogbo ọmọ Nàìjíríà - Afenifere

awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, other

Ẹgbẹ Afẹnifẹre tun ti ke gbajare sita lori ibi ti ọrọ abo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria bayii tun n gba lọ.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ naa, Kọmureedi Jare Ajayi fi sitalo ti sọrọ bẹẹ.

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ṣalaye pe ọrọ ti amugbalẹgbẹ fun Aarẹ Mohammadu Buhari, iyẹn, Garba Shehu sọ pe awọn agbesunmọmi fi ẹtan mu ki ijọba apapọ tu iyawo atawọn ọmọ adari ikọ agbebọn naa silẹ lai tu awọn eeyan ti wọn ji gbe ninu reluwe Abuja si Kaduna silẹ kii ṣe ohun to dun mọ awọn ninu rara.

Afẹnifẹre ni igbagbo gbogbo mutumuwa ni pe, ijọba yẹ ko lagbara ju ẹnikẹni tabi ẹlẹgbẹjẹgbẹ ni gbogbo ọna lorilẹede kan.

Bi eniyan ba si wo o pe ojuṣe ijọba ni lati pese abo ati igbayegbadun fun awọn eniyan rẹ, eeyan le sọ pe ijọba to wa lode bayii ti fidirẹmi ninu ṣiṣe awọn ojuṣe wọn. Itiju nla gbaa leyi.”

Garba Shehu ṣalaye ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ BBC Hausa so pe kii ṣe igba akọkọ niyi ti awọn agbebọn naa n kuna lati ṣika adehun to wa laarin awọn ati ijọba.

Amọṣa igba akkọ niyi ti ijọba apapọ yoo maa bọ si gbangba lati sọ pe awọn atawọn agbebọn n jijọ ni ajọṣepọ to mu adehun dani.

Nigba to n ṣapejuwe iṣẹlẹ iku akẹkọọbinrin Happiness Odeh ni Abẹokuta ati Omidan Rachael Ọpadele, akẹkọọ ileẹkọ giga fasiti LAUTECH nilu Ogbọmọṣọ ati ikọlu to waye nile ijọsin kan nipinlẹ Ondo loṣu kẹfa, Ẹgbẹ Afẹnifẹrẹ ni ina ọrọ abo to mẹhẹ ti jo dori koko bayii lorilẹede Naijiria bayii to si nilo ki Ijọba pakuru mọ ọ pẹlu igbesẹ to gbọngbọn.

Ẹgbẹ Afẹnifẹre wa ke si aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ko tete wa wọrọkọ fi ṣada lori didẹkun itajẹsilẹ to n waye nile, loko lodo lọna ọja.