Ọkùnrin kàn pàdánù ẹ̀mi rẹ ní ilé itùrà lẹ́yìn tí ó pàdé olólùfẹ́ orí ayélujára 

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ọkunrin kan ẹni ọdun marundilogota, Abdulwaheed Lamidi tí padanu ẹmi rẹ lẹyin ti o subu nigba ti oun ati ololufẹ gba yara si ninu ile ìtura kan ni agbegbe Ikotun ni Ipinlẹ Eko.

Lamidi ati ololufẹ ẹni ọdun mejilelogbon ni wọn pade lori ayelujara tí wọn sì pinnu lati fi oju ganni ara wọn lati ṣe tẹsiwaju ninu ere ifẹ lẹyin ọpọlọpọ ọsẹ lori ayelujara.

Arakunrin naa lo gbẹmi mi nigba ti o subu ni ile iwẹ lẹyin ti oun ati ololufẹ parí ere ifẹ wọn.

Alukoro fun Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ẹni ti o fidi iṣẹlẹ naa mule ni arabinrin naa nipe Lamidi gbẹmi mi nigba ti o subu lenu ọna baluwẹ.

Hundeyin ni awọn mọlẹbi Lamidi ti n seto lati gbe oku naa, ti wọn si ni awọn o setan lati ṣe ẹjọ lori iku to pa Arakunrin Abdulwaheed Lamidi.

"A ti ransẹ si awọn mọlẹbi Lamidi, ti n wọn siti bẹrẹ lati gbe oku naa kuro nile oku. Wọn si ni awọn ko setan lati ṣe ẹjọ lori iku Arakunrin naa.

"Arabinrin ololufẹ sì wa ni ahamo olopaa, ti o si bẹ ọlọpaa lati ma ṣe fun awọn obi òun."