Peter Obi kò lè rí tó alátìlẹyìn igba ni ìpínlẹ̀ Kaduna- El-Rufai

Aworan gomina ipinle Kaduna

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Gomina Ipinle Kaduna, Nasir El-Rufai tí fọwọgbaya pe olujide sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu Labour Party, Peter Obi ko ri to alatilẹyin ìgba tí yo darapọ mọ wọn saaju iwọde to fẹ waye ni Ipinlẹ Kaduna.

El-Rufai sọ eleyi lori opo ayelujara Twitter, nigba ti o fesi sì ikede kan tí ọkan lara awọn alatilẹyin Peter Obi gbe sì orí ayalujara "Kaduna Two Million March for Peter Obi".

Gomina ni iwọde naa ko le fẹsẹ mulẹ ni Ipinlẹ Kaduna

A ya fi ti ẹgbẹ oselu Labour Party ba lọ fi owo ko awọn eeyan wọle lati ipinlẹ miiran.

"Ẹrin yín pami, mo fi Ọlọrun bura.

Aworan ojo opo Twitter El Rufia

Oríṣun àwòrán, @elrufia

"Boya ẹ fẹ ko awọn eeyan ti wọn ki n sì sọọbu wọn lọjọ Aje wọle sì ipinle Kaduna.

"Ní ipinlẹ Kaduna, pelu awọn eeyan ti ẹ ba ko wọle mujumọ, mi ko ro pe ẹ le ri to eeyan igba fún ìwọde yín."

Siwaju eto ìdibo lọdun 2023, Peter Obi, olujide sipo aarẹ Orilẹede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oselu Labour Party bẹrẹ ìwọde naa, ti o si ti waye ni awọn ipinlẹ kan lorilẹede tí ọpọlọpọ eeyan sì darapọ mọ wọn.