Jigawa Floods: Ẹ̀kún omi ń bọ̀ yanturu ni Jigawa lẹyìn ikú èèyàn àádọta, ìjọba kìlọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Jigawa ti kesi awọn olugbe adugbo to sunmọ eti omi lati ko kuro nibẹ ni kiakia.
Ikilọ ati ikede yi n waye latara ibẹru pe omiyale agbaraya ṣọọbu mi yoo waye ni agbegbe ibẹ.
Gẹgẹ bi ajọ naa ṣe sọ, o kere tan eeyan aadọta lo ti padanu ẹmi wọn lọwọ omiyale yi ti ọkẹ aimoye si ti di alainile lori.
Ajọ naa fi kun pe iwadii awọn n tọka si pe ojo lile ṣi n bọ niwaju ti eleyi yoo si mu ki omi ti yoo wọ odo to so Hadejia papọmọ Jama'are kun lakunfaya.
Ọjọ mẹta gbako lojo ti n rọ leralera ni Jigawa
Ajọ to n risi ọrọ bi oju jọ ṣe ri ni Naijiria NIMET ti fi ikilọ sita pe ojo ti yoo rọ lapa ariwa kii ṣe kekere.
Ipinlẹ Jigawa si jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ lariwa ti o ti n koju omiyale sẹyin ti eleyi si ti ṣokunfa iku ọpọ eeyan.
Ni kopẹ yi ni BBC ba baba kan to padanu awọn ọmọ rẹ mẹta sọrọ nigba ti omi ya wọ inu iyara ti wọn sun si.
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni aadọta eeyan lo ti ba iṣẹlẹ omiyale lọ ti aimọye ile si ti dawo nitori omiyale yi.
- Kí ló ń fa ìjàmbá omíyale ní Naijiria?
- Kò sí ẹlẹ́gbẹ́ Atiku láàrín Tinubu àti Obi - Dino Melaye
- Adeleke tẹ́wọ́ gba kọ́míṣọ́nà Aregbesola sẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Ó ní àìríkanṣèkan lẹjọ́ tí Oyetola gbé lọlé ẹjọ́
- Wọ́n tí sìn Páṣítọ́ Shuaib Busari tí àwọn adigunjale ṣekúpa niluu ibadan
- Ìjàmbá iná pa olùjọ́sìn 41 lásìkò iṣẹ́ ìsìn lọ́jọ́ Àìkú
Awọn alaṣẹ Naijiria ti bẹrẹ si ni ṣeto iranwọ sawọn ti o padanu ile wọn lọwọ omiyale yi.
Yusuf Sani to jẹ alaga ajọ iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Jigawa sọ fun BBC pe kaakiri ipinlẹ naa ni ojo ti n rọ leralera fọjọ mẹta gbako.
''Lati ọjọ mẹta sẹyin ni agbara omi yi ti n san kaakiri ijọba ibilẹ mẹtadinlọgbọn.Ko si ibi ti ijamba yi ko gbalẹ de.''
O ṣalaye pe ''a ti sọ fawọn to n gbe lẹgbẹ omi lati ko kuro nibẹ''
Bakan naa lo ni awọn ti pese ibudo pajawiri fawọn ti ojo sọ di alainilelori.















