Adeleke tẹ́wọ́ gba kọ́míṣọ́nà Aregbesola sẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Ó ní àìríkanṣèkan lẹjọ́ tí Oyetola gbé lọlé ẹjọ́

Ademola adeleke

Oríṣun àwòrán, ademola adeleke/twitter

Gomina ti wọn ṣẹ̀ṣẹ dibo yan ni ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti sọ pe gbogbo nnkan to ba yẹ loun yoo fi duro ti iyansipo oun niwaju igbimọ iṣedajo ibo fun eto idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ọṣun.

Adeleke sọrọ idaniloju yii lasiko to fi n tẹwọ gba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC to le lẹẹdẹgbẹta niye sinu agbo ẹgbẹ oṣelu PDP lagbegbe ijọba ibilẹ Obokun.

O ni ofin ati ifẹ araalu lo gbe oun wọle sipo gomina ipinlẹ Ọṣun ti ọpọ “si mọ pe idibo naa lọ laisi ojoro.”

Kọmiṣọna iṣuna ati ato ọrọ aje labẹ iṣejọba Rauf Arẹgbẹṣọla gẹgẹbii gomina, Ọgbẹni Bọlọrunduro lo lewaju awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC to darapọ mọ PDP naa.

“Mo le sọ fun yin pe ofutufẹtẹ lasan ni. Mo lee sọ fun gbogbo awọn ololufẹ mi, gbogbo awọn to dibo fun mi pe ki wọn lọ fọkan balẹ.

“Lọtẹ yii, awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ti sọrọ. Ko si idi kankan fun wọn lati bẹru rara. Ifakoko ṣofo lasan ni.”

Adeleke wa fi da awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun loju pe eto ẹkọ, ilera ati abo pẹlu ipese ohun elo amayedẹrun ni awọn nnkan ti yoo mumu laya iṣejọba oun julọ.

Sẹnetọ onijo, gẹgẹ bi ọpọ ṣe maa n pe Sẹnetọ Ademọla Adeleke yẹ aga mọ gomina to wa lori oye lọwọ, Alhaji Gboyega Oyetọla nidi lasiko eto idibo gomina ipinlẹ ṣun to waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje.