Ìjàmbá iná pa èèyàn 41 lásìkò iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ kan

Aworan ijọ naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pupọ wọn ni wọn tẹ mọlẹ lasiko ti wọn n gbiyanju ati sa asala fun ẹmi wọn.

Awọn alaṣẹ sọ pe ko din ni eeyan mọkanlelogoji to ku ti ọpọ miran si tun fara ṣeṣe.

Iroyin sọ pe awọn ọmọde wa lara awọn ti wọn ku nibẹ.

Gẹgẹ bi awọn agbofinro ṣe fi to ileeṣẹ akoroyinjọ Reuters leti, Ina ṣẹyọ latara ohun elo amunawa kan nibi ti awọn eeyan bii ẹgbẹrun marun un ti n ṣe ijọsin ni ijọ Coptic Abu Sifin naa.

Ina naa di ẹnu ọna abajade eyi si fa ọpọlọpọ wọlukọlu bi otilẹ jẹ wi pe awọn panapana lorilẹede naa ni awọn ti pa ina naa.

Ko tii si ẹni to lee sọ ni pato ohun gan an to ṣokunfa ina ọhun.

Amọṣa o, oluṣọaguntan Farid Fahmy to jẹ fada ijọ kan nitosi ijọ ti ijamba ina ti ṣẹlẹ naa lagbegbe Imbaba ṣalaye fun ileeṣẹ akoroyinjọ AFP pe aṣemaṣe latara ohun elo ina manamana kan lo ṣokunfa ina naa.

Ki lawọn olujọsin sọ?

Aworan agbegbe ijọ naa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn olujọsin to wa ninu isin lasiko ti ijamba ina naa fi ṣẹlẹ ti n sọ iriri wọn.

Yasir Munir to jẹ ọkan ninu wọn ṣalaye pe, “Awọn eeyan n korajọpọ si aja kẹta ati ikẹrin ileejọisn naa la ba ri ti ina ṣẹyọ ni aja keji. Awọn eeyan ba sare n sọkalẹ ni wọn fi wa n ṣubu le ara wọn.”

“ Lẹyin eyi la n gbọ iro nla to n dun ti ọwọja ina ṣi n ṣẹyọ lati oju ferese”

O fi kun un pe isalẹ patapata loun ati ọmọbinrin oun wa lawọn fi raye tete sa asala.

Ki lawọn alaṣẹ lorilẹede Egypt n sọ?

Aarẹ orilẹede Egypt, Abdel Fattah al-Sisi ti ranṣẹ “ibanikẹdun si mọlẹbi awọn to ti lọ darapọ pẹlu Oluwa ninu ọkan lara ile ijọsin rẹ.”

Ọfiisi oluwadi agba lorilẹede naa ni oun ti fi awọn ọtẹlẹmuyẹ ranṣẹ sibi iṣẹlẹ naa lati lọ ree ṣe iwadii ohun to fa ajalu ina naa.

Awọn kiristẹni ijọ ilna ẹsin Coptic ni wọn ko ida miliọnu mẹwaa ninu eeyan miliọnu mẹtalelọgọrun to wa lorilẹede Egypt.