APC ní ìpínlè Oyo ló ní pé àwọn kò fẹ́ Adelabu mọ́, yée parọ́ mọ́ APC mọ́- Morka

Oríṣun àwòrán, @Presidency
APC sọ́ òkò ọ̀rọ̀ sí Adelabu lórí ìdìbò abẹ́nú
Ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ oselu APC, Felix Morka fi sita fun awọn akọroyin ni gbogbo ọrọ ti Adebayo Adelabu sọ lo jẹ ọrọ ti ko yẹ ki o jade lenu Adebayo Adelabu.
Morka ni awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC ni Ipinlẹ Oyo lo ni awọn ko fẹ Adebayo Adelabu gẹgẹ bi olujide sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu APC ni Ipinlẹ Oyo.
O tẹsiwaju pe gbogbo ẹsun tí olujide sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu Accord Party fi kan awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC ni o jẹ irọ.
"Awọn ọmọ ẹgbẹ oselu All Progressive Congress nipinle Oyo lo yan ẹni ti wọn fẹ.
APC Oyo dáa padà fún Adebayo Adelabu pé ọ̀rọ̀ tó sọ kò tọ́ síi lẹ́nu rárá ti pé irọ́ ni o n pa mọ́ APC- Felix Morka "Lẹyin ti Adebayo Adelabu kuro ninu ninu ẹgbẹ oselu APC, to yẹ ko gbajumọ bi yoo ṣe ṣe agbekalẹ eto ìjọba rẹ tí ko fẹsẹ mulẹ, ó bẹrẹ lati pa irọ nlanla mọ ẹgbẹ oselu APC.
“A fi Ọlọrun sìn Adelabu sugbọn ko dẹkun lati ma irọ ẹgbẹ oselu APC ati awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa."
Ẹgbẹ oselu All Progressive Congress ti fesi lati bu ẹnu atẹlu ọrọ ti olujide sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu Accord Party ni Ipinlẹ Oyo, Adebayo Adelabu sọ lori bi eto ìdibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC ṣe waye.
Adelabu ni ti wọn ba fi da oun, eto ìdibo abẹnu APC ko waye ni Ipinlẹ Oyo nítorí ẹgbẹ naa kọ lati tẹle ilana ajọ eto ìdibo INEC.
O tẹsiwaju pe awọn sẹneto marun un ninu ẹgbẹ oselu APC gba ẹtọ oun lọwọ oun nítorí oun kọ lati ditẹ oludjide sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.
Igbakeji gomina banki apapọ nigba kan rí, darukọ Aarẹ ile igbimọ aṣòfin Ahmed Lawan, Sen Abdullahi Adamu, Sen Iyiola Omisore, Sen Tokunbo Afikuyomi ati Sen Teslim Folarin gẹgẹ bi awọn to le di apupọ lati ja lole dibo gomina.
Àwọn Sẹ́nétọ̀ márùn-ún ló jami lólè tí mò fí kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC - Adelabu

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Oloye Adebayo Adelabu, tó n dije sipo gomina lẹgbẹ Accord Party ni Ipinlẹ Oyo ti sísọ lori bi irinajo rẹ pẹlu ẹgbẹ oselu All Progressive Congress ṣe wa sopin.
Oloye Adebayo Adelabu, olujide sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu Accord Party ni Ipinlẹ Oyo ti sísọ lori bi irinajo rẹ pẹlu ẹgbẹ oselu All Progressive Congress ṣe wa sopin lẹyin idibo abẹnu ẹgbẹ oselu naa.
Adelabu, ẹni ti o gba asia ẹgbẹ oselu APC lọdun 2019, ti o si lulẹ ni awọn agba ọjẹ ninu ẹgbẹ oselu APC lo le oun kuro ninu ẹgbẹ naa lẹyin ti wọn ja oun lole.
Nigba ti sísọ loju lori redio kan niluu ibadan, Adelabu durukọ awọn marun-un to ledi apupo lati le kuro ninu ẹgbẹ oselu APC, ti o fi dero ẹgbẹ oselu Accord Party saaju eto ìdibo gomina ti yo waye lọdun 2023.
Adelabu fẹ sun kan awọn sẹnẹto marun-un : Alaga fun ẹgbẹ oselu APC, Abdullahi Adamu, Aarẹ ile igbimọ aṣòfin, Ahmed Lawan, Akọwe ẹgbẹ oselu APC, Iyiola Omisore, Sen. Tokunbo Afikuyomi ati olujide sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu APC ni Ipinlẹ Oyo, Sen. Teslim Folarin.
O tẹsiwaju pe awọn ti wọn durukọ ja oun lole nítorí ibaṣepọ oun ati olujide sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC,
Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, ti wọn si gbero lati yan Ahmed Lawan gẹgẹ bi olujide sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC dipo Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.
Adelabu ni oun yọwọ kuro ninu idibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC lẹyin ti o han si gbogbo ẹgbẹ pé awọn kan fẹ fi tipatipa yan olujide sipo gomina.
"Ẹ jẹ ki sọ pe wọn jami lole nitori ibaṣepọ mi pẹlu Asiwaju Bola Ahmed Tinubu. Awọn sẹnẹto marun-un lo ledi apupo lati yan Lawan gẹgẹ bi olujide sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC.
“Àwọn sẹnẹto bí, Aarẹ ile igbimọ aṣòfin Ahmed Lawan, Sen Abdullahi Adamu, Sen Iyiola Omisore, Sen Tokunbo Afikuyomi ati Sen Teslim Folarin.
"Wọn lẹ di apupo lati yan Folarin nigba ti wọn mọ pe emi ko ni sisẹ tako Tinubu.Adelabu ni ko si ìdibo abẹnu APC kankan ní ìpinlẹ Oyo nítorí pe eto ilana ìdibo abẹnu naa lodi si ofin ajọ ìdibo INEC.















