Mattawale Bandits: Wo ìdí tí Gómìnà fí ní kí wọn yìnbọn pa ọlọ́kadà tó bá tápà sí òfin kónílé-ó-gbélé alẹ́

Gomina ipinlẹ Zamfara Bello Mattawale ti fofin de wiwa ọkada ni olu ilu ipinlẹ naa Gusau laarin ago mẹjọ alẹ si ago mẹfa owurọ.
O tun paṣẹ fawọn agbofinro lati yinbọn pa ẹnikẹni to ba lodi si aṣẹ tuntun to gbe kalẹ yi.
Igbesẹ naa gẹgẹ bi o ṣe sọ jẹ eleyi ti awọn gbe lẹyin ipade igbimọ eto aabo Zamfara lati dena lilo ọkada fi ṣe iṣ aburu awn janduku ni Gusau ati ayika rẹ.
Lasiko to n ba awọn eeyan ipinlẹ naa sọrọ lori ẹrọ anohunmaworan lo ti fi ọrọ yi lede.
- Wo ojú àwọn jàndùkú afẹ̀mí-ṣòfò tó sọ ará wọn di gàba ní àríwá Nàìjíríà - BBC News Yorùbá
- Ìhá Buhari àtìjọba rẹ̀ sọ́rọ̀ ìjínigbé ń gbin ẹ̀rù sọ́kàn gbogbo ọmọ Nàìjíríà - Afenifere
- Àwọn jàndùkú tún ṣọṣẹ́ ní Zamfara, wọ́n pa ọlọ́pàá kan àti olórí fijilanté
- APC ní ìpínlè Oyo ló ní pé àwọn kò fẹ́ Adelabu mọ́, yée parọ́ mọ́ APC mọ́- Morka
O ni''pẹlu bi ọwọja idunkoko awọn janduku ni eti bebe Gusau ṣe n peleke si, a fi ofin de wiwa ọkada laarin ago mẹjọ al si mẹfa owurọ ni gbogbo agbegbe to yi Gusau ka''
"Lara awọn agbegbe yi la ti ri Mareri, Damba, Tsunami, Tsauni, Barakallahu, Samaru, Gada Biyu, ati Janyau East.''
Ofi kun pe ''a ti fawọn agbofinro ni aṣẹ lati yinbọn lu ẹnikẹni to n gun ọkada lasiko yi to si kọ lati duro ni Gusau tabi layika ilu naa''
Ipinlẹ Zamfara jẹ oju ina ninu awọn ipinlẹ lariwa Naijiria ti ipenija aabo jẹ ohun to n kan raalu lominu.
- Wa kùsà kóo dáràn! Àṣẹ tuntun tó kalẹ̀ ní Zamfara
- Ìjọba àpapọ̀ rán 1000 ọmọ ogún lọ sí Zamfara
- Ọkùnrin kàn pàdánù ẹ̀mi rẹ ní ilé itùrà lẹ́yìn tí ó pàdé olólùfẹ́ orí ayélujára-
- Wo bí àwàdà tí adẹ́rìnpòṣónú ṣe pé àwọn adigunjalé ń bọ̀ wá sí bánkì ṣé sọ adẹ́rinpòṣónú di èrò ẹ̀wọ̀n
- Wo ìdí tawon agbebọn fi tu mẹta nínú arinrinajo reluwé Abuja sí Kaduna sílẹ̀
- Àwọn afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn yìnbọn pa ọmọ ọba l'Osun
- Ààrẹ Buhari gbéra lọ Liberia láti gbàwọ́n ní ìmọ̀ràn lórí ètò ààbò
Ijinigbe lọwọ awọn janduku agbebọn ko jẹ nkan tuntun nibẹ.
Ijọba apapọ ati ti ipinl n gbe awọn igbesẹ lati da alaafia pada ki wọn si doju ija kọ awọn alaburu to n gba owo lọwọ awọn ti wọn jigbe tabi ki wọn si ṣeku pa lomiran.
Bi a ko ba gbagbe ileeṣẹ BBC gbe fidio iwadii ọtẹlẹmuyẹ kan jade lori aburu tawọn janduku agbebọn yi n ṣe ni paapaa nipinlẹ Zamfara.















