Wo ojú àwọn jàndùkú afẹ̀mí-ṣòfò tó ń hùwà tani-ó-múmi ní àríwá Nàìjíríà

Àkọlé fídíò, BBC Africa Eye: ojú àwọn jàndùkú afẹ̀mí-ṣòfò tó sọ ará wọn di gàba ní àríwá Nàìjíríà rèé

Ojoojumọ lawọn eeyan ariwa Naijiria fi n ke irora lori ipenija aabo to n koju wọn lagbegbe naa.

Bi ere bi ere o si ti wa di ranto debi pe ẹmi ko j awọn alaburu afẹmiṣofo loju mọ.

Ninu iwadii ọtẹlẹmuyẹ BBC Africa Eye tuntun ti a gbe jade, a ṣafihan diẹ ninu awọn to wa nidi iwa janduku ajinigbe agbebọn ni ariwa Naijiria.

Iwadii yi gbe wa lọ inu igbo kijikiji nibi tawọn janduku yi ti n leri leka pe awọn agbofinro ijọba ko to bẹẹ lati wa wọn kan nibẹ.

Iwadii yii tubọ gbọ ọrọ lẹnu awọn ti wọn farakasa ikọlu awọn ajinigbe afẹmiṣofo yi.

Pataki julọ a tan imọlẹ si bi ija ẹlẹyamẹya naa ti ṣe n dakun wahala aisi ifọkanbalẹ, iṣipopada ati aibalẹ ọkan to gbode ni ariwa Naijiria ni paapaa ipinlẹ Zamfara.