Àwọn agbébọn sẹ fídíò bí wọ́n sẹ n na àwọn arìnrìnàjò Abuja sí Kaduna

Aworan

Oríṣun àwòrán, Other

Awọn agbebọn ti wọn ji awọn arinrinajo oju irin lati Abuja si Kaduna ti fi fidio tuntun sita nibi ti wọn ti n lu wọn bi bara.

Fidio naa to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara naa ni o safihan awọn arinrinajo naa ti wọn ke pẹlu irora bi awọn agbebọn naa ṣe n na wọn.

Ninu fidio naa to kọnilominu ni a ti gbọ ohun eniyan kan to n sọ fun awọn agbebọn naa pe ki o jọwọ maṣe na awọn arinrinajo naa mọ.

Ẹni naa n sọ wipe Ali, Abdullahi ye na awọn eniyan yii mọ, fi wọn silẹ.

Lẹyin naa ni ọkan lara awọn arinrinajo naa n ṣalaye bi awọn ajinigbe naa ṣe ji wọn gbe ati bi ijọba ṣe kọ lati wa doola ẹmi wọn.

Bakan naa ni wọn wa kesi awọn ajọ ni agbaye ati orilẹede ni orilẹede Amẹrika, Ilẹ Gẹẹsi ati Ilẹ Faranṣe lati jọwọ wa doola ẹmi wọn, ti wọn si n ke rora pe ijọba to yẹ ko doola ẹmi wọn ti kuna lati ṣe ojuṣe wọn.

O ni o da awọn loju pe awọn to ji wọn gbe ko fẹ fi wọn si panpẹ fun igba pipẹ.

Obinrin naa to tun sọrọ pẹlu ipaya sapejuwe ijọba Naijiria gẹgẹ bi orilẹede to kuna lati doola awọn eniyan rẹ lẹyin ti wọn dibo yan wọn.

Bakan naa ni agbebọn kan sọrọ nibẹ to si ni ijọba lo n doju ti awọn eniyan rẹ pẹlu bi wọn ṣe kọ lati ṣe ohun to tọ.

Awọn agbebọn dunkoko lati ji awọn olosẹlu nla nla gbe lọ

Agbebọn naa to sọrọ ninu fidio naa ni awọn mọ pe ẹtọ ijọba ni lati doola ẹmi awọn eniyan wọn.

Gẹgẹ bi a ṣe sọ tẹlẹ, ni kiakia ẹ mu adehun yin ṣẹ,nitori ti ẹ ko ba ṣe ni kiakia, ohun ti a maa ṣe a buru ju eyi lọ.

Agbẹbọn naa tun dunkoko lati ji awọn oloṣelu nla nla gbe lọ, to fi mọ awọn ṣenetọ ni Naijiria.

Oṣu to kọja ni awọn agbebọn naa fi awọn arinrinajo kọọkan ti wọn jigbe silẹ laarin awọn ti wọn jigbe lẹyin ti wọn san ẹgbẹgbẹrun miliọnu dola owo ilẹ okeere.

Iwadii fihan pe eniyan to to mẹtalelogoji ṣi wa ni ikawọ wọn.

Ninu ọrọ ẹni to doola awọn eniyan ti wọn kọkọ fi silẹ, o ni ijọba aarẹ Buahri lo kuna lati mu adehun rẹ ṣẹ ki wọn le fi awọn ti wọn mu naa silẹ.

Laipẹ yii ni aarẹ Buhari paṣẹ ki awọn adari ẹṣọ alaabo ni Naijria sa gbogbo ipa wọn lati ri pe wọn soola ẹmi awọn ti wọn jigbe naa.