Ààrẹ Buhari bá wa dóòlà ẹ̀mí àwọn molẹ́bí wa! - Ẹbí àwọn arìnrìnàjò tí wọ́n jígbé ní ojú irin Abuja sí Kaduna fígbeta

Aworan

Awọn mọlebi awọn ti wọn jigbe ni oju irin Abuja si Kaduna ti fi aidunnu wọn han si aarẹ orilẹede Naijiria Muhammadu Buhari.

Awọn mọlẹbi naa lo fi aidunnu wọn han lasiko ti wọn n ṣe iwọde ni ilu Abuja ni iwadu ileeṣẹ ijọba to n risi eto irinna.

Aworan

Awọn ẹbi se ètò ìwọ́de nílùú Abùjá naa nitori awọn ẹbí wọn tó wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé.

Aworan

Wọn kesi ijọba aarẹ Buhari lati jọwọ doola ẹmi awọn eniyan wọn to wa ni ahamọ.

Aworan

Wọn bẹbẹ ki wọn ran awọn lọwọ ki awọn mọlẹbi wọn le pada ni ayọ ati alaafia.

Aworan

Laipẹ yii ni awọn agbebọn fi fidio sita nibi ti wọn ti n na awọn arinrinajo naa to wa ni ahamọ wọn.

Buhari àti El-Rufai la fẹ́ jígbé báyìí - Àwọn agbébọn, Irọ́ lẹ pa - ìjọba fèsì

Awon agbebon

 Àwọn agbébọn tí wọ́n jí àwọn èrò inú ọkọ̀ ojú irin tó ń ná Kaduna sí Abuja gbé nínú oṣù Kẹta ọdún 2022 ti dúnkokò láti jí Ààrẹ Muhammadu Buhari gbé.

 Bákan náà ni wọ́n ní àwọn tún máa jí Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai gbé láìpẹ́.

 Nínú fọ́nrán kan tí àwọn agbébọn náà fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Keje ní àwọn olóṣèlú ńláńlá ni àwọn fẹ́ máa jí gbé báyìí.

Fọ́nrán náà ṣàfihàn bí àwọn ajínigbé náà tí a lérò wí pé wọ́n jẹ́ ikọ̀ Boko Haram ló ṣàfihàn bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn ènìyàn tó wà ní àhámọ́ wọn.

 Ẹnìkan tó sọ̀rọ̀ gba tẹnu àwọn yòókù rẹ̀ ní lágbára Ọlọ́run àwọn ṣì ma jí Ààrẹ Buhari àti El-Rufai gbé sí àhámọ́ wọn.

Òfo ni fọ́nrán tí àwọn agbébọn fi síta lórí àwọn tí wọ́n jí gbé - ìjọba àpapọ̀

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna kò ì tíì sọ ohunkóhun lórí fídíò náà àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ni El-Rufai ti máa ń sọ ọ́ wí pé ohun tó le tán ìṣòro àwọn agbébọn ni kí ìjọba pa wọ́n lẹ́ẹ̀kan náà.

 Ẹ̀wẹ̀, ìjọba àpapọ̀ ti ní fídíò tí àwọn náà agbébọn náà fi léde jẹ́ láti fi dẹ́rù bá àwọn ènìyàn lásán ni.

 Agbẹnusọ Ààrẹ Buhari, Mallam Garba Shehu nígbà tó ń bá BBC sọ̀rọ̀ ní káàkiri àgbáyé bí àwọn agbébọn ṣe máa ń ṣe láti fi dẹ́rù bá àwọn ènìyàn nìyẹn.

 Shehu ní òfo ọjọ́ kejì ọjà ni fídíò náà nítorí àwọn agbébọn náà mọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣé láti fi dẹ́rù bá ìjọba kí ìjọba le gba nǹkan tí wọ́n fẹ́. 

Ó ní fídíò náà kò jẹ́ tuntun sí àwọn nítorí ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí àwọn agbébọn náà ń fi irú rẹ̀ síta àti pé ó tún le ma jẹ̀ẹ́ ìgbà ìkẹyìn.

 Ó fi kun pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé wọ́n ń wá ọ̀nà láti gba owó lọ́wọ́ ìjọba tàbí gba nǹkan mìíràn ni wọn fi gbé fídíò náà síta.

 Bákan náà ló ní àwọn fídíò náà kìí se èyí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe nítorí ohun tí wọ́n ń bèèrè nínú fídíò náà ni àwọn tí jọ jíròrò lé lórí tẹ́lẹ̀.

Shehu ní òun mọ̀ wí pé inú ẹbí àwọn tí ènìyàn wọn wà níbẹ̀ kò le dùn sí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ àti pé ohun tó lè mú inú wọn dùn ni kí àwọn ènìyàn wọn padà sílé.

 Ó ní ó ṣeni láàánú wí pé ètò ààbò di kúrẹtẹ̀ nítorí gbogbo ohun tó yẹ ni Ààrẹ Buhari ń ṣe lórí ètò ààbò.

 Bẹ́ẹ̀ náà ló ní ìgbésẹ̀ ti ń lọ láti tú àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láìpẹ́ àti pé ohun tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò nílò ni àtìlẹyìn àwọn ará ìlú.